Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnọrebu Suraju Iṣọla Adekumbi ti gbe oṣuba kare fun ajọ eleto idibo lorile-ede Naijiria fun idibo to n lọ lọwọ yi, latari awọn atunṣe ati agbeyẹwo awọn iṣoro to koju wọn at'awọn oludibo ninu idibo to kọja lọ.

Ọnọrebu Iṣọla Adekumbi lo gbe oriyin fun ajọ INEC lasiko to n dibo ni wọọdu ẹ to wa ikorita Mẹkaniiki, Unit 14, Ayetoro laipẹ yi.
O sọ pe nigba toun fẹẹ dibo to lọ lọhun, oriṣiriṣi ipenija lawọn eeyan koju, toun naa si pẹlu awọn ti ẹrọ ti wọn fi n yẹ awon to kun oju oṣuwọn lati dibo wo, ti ẹrọ naa ko si gba ọwọ oun wọle.
Abẹnugan naa ni pẹlu nnkan toun ri nibi toun ti dibo naa, oun rii pe ayipada gidi ti de ba ajọ INEC, nitori pe ko si ipenija kankan lasiko yi.
Bakan naa nigba to n sọ b'awọn eeyan ṣe jade lati dibo, Adekumbi ni inu oun dun lati ri bi ọpọ awọn araalu ṣe jade sita ju tidibo to kọja lọ.
O ni ko si nnkan meji to mu k'awọn eeyan ma jade dibo lakọkọ bi ko ṣe ti ibẹru eto aabo, ṣugbọn ni bayii, ọkan wọn balẹ pe eto aabo to peye wa daadaa.
No comments:
Post a Comment