Boroboro lawọn ọrẹ meji kan ti wọn ko niṣẹ meji ju ole jija lọ
n ka bayii nigba tọwọ awọn fijilante, iyẹn VSO tẹ
wọn
lọjọ Tuside ọsẹ to lọ lọhun lagbegbe Owode Yewa, ipinlẹ
Ogun.
Akorede Surajudeen, ẹni
ọgbọn
ọdun
ati Abiọdun
Adelakun, ọmọdun mọkandinlọgbọn la gbọ pe ọwọ tẹ, nigba ti wọn si n ṣewadi ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Bọde, ẹni ti wọn loun lo ra mọto naa ni Bẹnin.
Ohun ta a gbọ pe o ṣakoba fun wọn ni mọto jiipu GL 4MATIC ti wọn
lọọ ji gbe
niluu Ajah, iyẹn
l’Eko lọjọ kẹrinla oṣu keji to kọja yi, ti wọn si lọ ta a danu lẹsẹkẹsẹ sorileede Bẹnin,
iyẹn
Kutọnu.
Nigba taṣiri maa tu, ọga awọn fijilante tipinlẹ
Ogun, VSO,
Ọgbẹni
Sọji
Ganzallo ni wọn
loo fọrọ naa to leti pe ko ba wọn
wa n kan ṣe
si, oun lo si ta gbogbo awọn oṣiṣẹ ẹ lolobo pe ki wọn
bẹrẹ iṣẹ iwadii ni kiakia.
AWIKONKO gbọ ni pe lẹsẹkẹsẹ ti olobo ti ta wọn
la gbọ
pe wọn
ti bẹrẹ iwadii, ko da a tawọn oṣiṣẹ wọn lagbegbe Idiroko to sunmo Bẹnin
naa ti bẹrẹ iwadii. AWIKONKO gbọ
pe ọjọ Tuside ọsẹ to kọja laṣiri awọn ọdaran naa tu ni nnkan bi aago mẹfa
kọja
iṣẹju mẹẹdogun.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ẹgbẹ fijilante nipinlẹ
Ogun,
Ọgbẹni
Mọruf
Yusuf sọ
pe lẹsẹkẹsẹ
tọwọ
ti tẹ
awọn
ọdaran
ni wọn
ti ka gbogbo iwa buruku
ọwọ wọn lai kii ṣe pe awọn dana iya fun wọn.
Ọgbẹni
Mọruf
sọ
pe awọn
eeyan naa jẹwọ
pe ẹnikan to jẹ Bọde to maa n gba ẹru
tawọn
ba ji gbe
lawọn
ta a fun ni Bẹnin,
ati pe ninu miliọnu
meji aabọ
owo Bẹnin, iyẹn cefa, miliọnu kan ataabọ (1.400.000cefa) lawọn
ṣi
gba lọwọ ẹ.
O wa jẹ ko ye wa pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe kawọn ko awọn ọdaran naa lọ sọdọ awọn ọlọpaa Idiroko lati tẹsiwaju
iwadii. Gbogbo akitiyan lati gbọ tẹnu alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi lo ja si pabo titi dasiko ta a kọ
iroyin yi tan.
No comments:
Post a Comment