Aisha Buhari lasiko to n gbalejo lati ṣayẹyẹ bi ọkọ
rẹ ṣe jawe olubori sọ wi pe, Aarẹ yoo gbogun ti iwa ibajẹ, iṣẹ ti oṣi eleyii ti
yoo mu opin ba alafo to wa laaarin awọn olowo ati awọn alaini ni awujọ.
Iyawo aarẹ naa dupẹ lọwọ awọn obinrin ati ọdọ fun
atilẹyin wọn lasiko idibo naa.
Bakan naa ni aarẹ Muhammadu Buhari ti wọn ṣẹṣẹ yan
fun saa keji naa sọ wi pe oun mọ ipa ribiribi ti awọn obinrin ati ọdọ ko lasiko
idibo naa, nitori naa oun yoo yan awọn obinrin sipo lati ba oun ṣiṣẹ.
Amọ, Aarẹ Buhari ni awọn obinrin to ni iwa ọmọluwabi
to si fẹran orilẹede Naijiria ni oun yoo yan sipo.
Aarẹ naa fikun ọrọ rẹ wi pe oun yoo pese ohun ọgbin
fun awọn agbẹ aroko ni iye owo ti ko kan ni leegun ẹyin, ki o ba le mu iwuri ba
awọn ọdọ lati mu iṣẹ agbẹ lokunkundun.
- BBC
No comments:
Post a Comment