WỌN YINBỌN PA ỌGA AGBA TUBU NIPINLẸ KOGI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 5, 2019

WỌN YINBỌN PA ỌGA AGBA TUBU NIPINLẸ KOGI

 

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Titi di asiko ti a n kọ iroyin yi tan, awọn ọlọpaa, paapaa gbogbo awọn to n ri si eto aabo nipinlẹ Kogi la gbọ pe wọn ti bẹrẹ iwadii lori awọn to pa igbakeji ọga agba tẹlẹri nileeṣẹ to n ri si ọrọ tubu nipinlẹ naa, Dọkita Adewale Oloyede.

Ọjọ Mọnde ana la gbọ pe awọn adigunjale lọọ dena de ọkunrin naa pẹlu ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ ẹ, Dauda Michael.

Alukoro ileeṣẹ naa, Ọgbẹni Francis Enobore lo kede ọrọ naa sita nirọlẹ ana, oun naa lo si jẹ ka mọ pe agbegbe Ọsara ni wọn ti pa wọn lọjọ kinni in oṣu yi, iyẹn ọjọ Fraide ọsẹ to kọja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI