Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Gomina ipinlẹ Plateau, Simon
Lalong ti kede sita pe gbogbo ọjọ keji ninu oṣu keji lọdọọdun ni yoo maa jẹ ọjọ
idariji ẹṣẹ, ati pe ọjọ naa yoo tun ni ọlude nipinlẹ naa.
Oni tii ṣe tọside ni Gomina
Lalong sọrọ naa nibi ti wọn ti fi ọgba kan ti wọn pe ni Ọgba Alaafia ati
Idariji, iyen Garden of Peace and Forgiveness lelẹ niluu Jos.
O sọ pe “Gẹgẹ bi gomina ipinlẹ
yi, mo duro lorukọ awọn eeyan rere nipinlẹ Plataeu lati tọrọ idariji lọwọ
gbogbo awọn ọmọde ti wọn ti padanu awọn obi wọn nitori aile ṣe deede wa.
“A bẹbẹ fun idariji awọn obi ti
wọn padanu awọn ọmọ wọn ninu ajalu nla to fitan buruku balẹ gẹgẹ bi eeyan
alaafia.
“A tọrọ idariji lọwọ gbogbo
ọkunrin ti wọn padanu iyawo wọn nigba ti a kuro ninu eeyan rere sinu eeyan
buruku. A tọrọ idariji lọwọ awọn obinrin ti wọn padanu ọkọ wọn latari iwa were
ọwọ wa, eyi to gba idariji ju ka maa ranti lọ.
“Oni jẹ ọjọ irin ajo itan gẹgẹ
bi awa eeyan ipinlẹ Plataeu. Nitori to jẹ gẹgẹ bi ọjọ idariji. ọjọ ti a ti ya
sọtọ lati farahan ninu irin ajọ wa gẹgẹ bi eeyan, ti yoo si maa wa lọkan wa
nipa awọn ajalu oriṣiriṣi to ti n kọlu wa nipinlẹ yi lati ọdun 2001."
Gomina Lalong wa a rawọ ẹbẹ
sawọn ọmọ ipinlẹ naa lati tan ọrọ idariji naa kaakiri gbogbo ipinlẹ naa, ki
alaafia le tubọ jọba.
No comments:
Post a Comment