Bo tilẹ jẹ pe iwadi ṣi n lọ lọwọ lori iku gbajumọ pasitọ ṣọọṣi Anglican Communion kan ti wọn ṣẹṣẹ gbe lọ siluu Ṣokoto, Refurẹndi Jonathan Auta, sibẹ, kayeefi niku ẹ ṣi n jẹ fawọn eeyan, paapaa awọn ọmọ ṣọọṣi ẹ.
Ohun ta a gbọ ni pe awọn
agbebọn kan ni wọn jii gbe, ti wọn si n beere miliọnu mẹwaa naira lọwọ awọn ṣọọṣi
ẹ ki wọn too le fi silẹ, ati pe wakati kan pere ni wọn lawọn agbebọn naa fẹẹ fi
gba owo yi.
A gbọ pe asiko ti Pasitọ naa
atawọn ẹbi ẹ n rin irin ajo lọ lati Ṣokoto siluu Zamfara la gbọ pe awọn agbebọn
naa pade wọn lọna, ti wọn si ji wọn gbe, iyẹn lagbegbe Talatan-Fara ni Kauran
Namoda.
Nigba ti wọn ko tete ri owo naa, lo mu ki wọn
pa Pasitọ naa danu lati le fi ye wọn pe awọn ko ṣere rara, ti wọn si lọọ ju oku
ẹ sibi ti wọn ti maa tete ri i.
Titi dasiko ta a kọ iroyin yi
tan la gbọ pe awọn ẹbi oloogbe naa ṣi wa lahamọ awọn ajinigbe naa.
No comments:
Post a Comment