Kayeefi n’iku ọdọmọbinrin kan
ti wọn pe oruọ rẹ ni Ezeobi Oluchukwu ṣi jẹ titi dasiko ti a ṣe akojọpọ iroyin
yi tan pẹlu bawọn kan ta a ko tii mọ wọn, ṣugbọn tawọn ọlọpaa ṣi n ṣe iwadii
wọn lọwọ ṣe gun un pa lọjọ Mọnde ijẹta.
Ohun ta a gbọ ni pe aarọ kutu
lasiko ti Ezeobi tawọn eeyan tun n pe ni Luchy Belle n ṣe idaraya lọ lawọn
ọdaran naa lọọ koju ẹ, iyẹn niluu Akwa, ipinlẹ Anambra, ti wọn si gun un pa.
Ezeobi ti wọn loo yan iṣẹ awọn
to n ṣe oju loge laayo, ni wọn lawọn to pa a naa tun gba foonu rẹ salọ lẹyin ti
wọn da ẹmi ẹ legbodo tan.
Mọṣuari kan to wa nitosi ibi ti
wọn pa a si la gbọ pe awọn ọlọpaa gbe e lọ fun ayẹwo.
AWIKONKO gbọ pe lati bi ọjọ meloo kan sẹyin lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti n pa ara wọn danu, ti wọn tun n pawọn eeyan bo ṣe wu wọn, ta a si gbọ pe wọn ti pa eeyan ti ko din ni mẹfa bayii.
No comments:
Post a Comment