Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Ile ẹjọ giga kan to fikalẹ
siluu Ado-Ekiti ti paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun ọrẹ mẹta kan, latari ẹsun ole
jija ti won fi kan wọn, ati pe awọn ọrẹ meji naa la gbọ pe wọn ko niṣẹ meji ju
ole jija lọ.
Oni Tọside ni Onidajọ John
Adeyẹye gbe idajọ naa kalẹ fawọn ọrẹ meji yii, Oluwayọmi Adedayọ, ẹni ọdun
mẹtadinlọgbọn (27) ati Ṣeyi Daramọla toun jẹ ọmọdun mẹtalelogun
Onidajọ naa, Adeyẹye sọ pe ki i
ṣe pe oun dee de da ẹjọ naa fun bi ko ṣe pe ko si awijare lori ẹsun ti wọn fi
kan wọn naa, nitori pe ṣe ni wọn jẹbi patapata.
AWIKONKO gbọ pe ọdun 2016, iyẹn
ọjọ kẹrin oṣu kẹjọ ni Daramọla ati Adedayọ ti jale naa nile igbafẹ kan ti wọn
pe ni Club 15, Dynamic Lounge lagbegbe Irewumi, nitosi Bawa niluu Ado-Ekiti.
Awọn mejeeji la gbọ pe ọjọ
kẹrindinlogun oṣu kẹwaa ọdun 2017 ni wọn foju wọn bale ẹjọ, ọjọ naa la si gbọ
pe awọn mejeeji sọ pe lootọ lawọn jẹbi ẹsun meji ọtọọtọ ti wọn fi kan wọn.
A gbọ pe ibọn lawọn mejeeji mu
lọọ fi pawọn eeyan lẹkun lọjọ naa, ti wọn si gba ẹrọ kọmputa ati foonu
oriṣiriṣi nibẹ. Nigba taṣiri wọn maa tu, wọn nibi ti wọn ti n gbiyanju lati ta
awọn nnkan ti wọn ji naa lọwọ ti tẹ wọn nigba ti wọn sọ pe wọn ko mọ bi wọn ṣe
le ṣi awọn nnkan naa fawọn ti wọn fẹẹ ta wọn fun.
No comments:
Post a Comment