Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
Gbogbo eto lo ti pari bayii fun
ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Najiria lati ti gbogbo ipinlẹ Ogun pa pẹlu iwode
ifẹhonu han ti wọn fẹẹ ṣe nitori bi wọn ṣe sọ pe Gomina ipinlẹ naa, Ibikunle
Amosun jẹ awọn oṣiṣẹ lowo rẹpẹtẹ, ti ko si fẹẹ san owo naa ko too lọ.
Iwọde naa ta a gbọ pe alaga
ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, Kọmureedi Ayuba Waba fẹẹ lewaju ẹ ni wọn ti
so pe ọjọ Fraide ọsẹ yi ni wọn fẹẹ ṣe kaakiri ipinlẹ Ogun, bẹrẹ lati ilu
Abẹokuta to jẹ olu ipinlẹ naa.
Ninu lẹta ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kọ
ranṣẹ si Gomina Amosun lọjọ Wẹside ọsẹ to kọja, eyi ti ẹda ẹ tẹ AWIKONKO lọwọ
laipẹ yi ni wọn ti sọ pe koko iwọde naa da lori bi Gomina Amosun ṣe n ṣe awọn
oṣiṣẹ niṣekuṣe.
Koko ọrọ ti wọn fi sọri iwọde
naa ni wọn pe ni ‘Ẹ Gba Ipinlẹ Ogun’ (Operation
Occupy Ogun State) pẹlu iwa Lilodi s’awọn oṣiṣẹ, iyẹn (Anti-Worker Actions) ti ijọba Gomina Amosun n hu nipinlẹ naa.
Ninu lẹta naa ni alaga patapata
fawọn oṣiṣẹ orileede Naijiria, Ayuba Wabba ti sọ pe iwọde tawọn fẹẹ ṣe lọjọ
Fraide ọsẹ yi yoo gba kawọn ti ipinlẹ Ogun pa titi ti Gomina Amosun yoo fi
dawọn lohun nnkan ti wọn n fẹ.
Lara awọn nnkan ti wọn n beere
lọwọ Gomina Amosun gẹgẹ bi wọn ṣe kọ ọ sinu lẹta naa ni owo osu ti Gomina jẹ
wọn, owo ajẹẹlẹ ati owo alajẹṣẹku ti Gomina kọ lati fun wọn.
Eyi to tun jẹ koko inu ẹ ni bi
Gomina Amosun ṣe kọ lati da alaga awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Akeem
Ambali pada sipo to wa tẹlẹ ati tawọn oṣiṣẹ ti ileewe giga Tai Ṣolarin to wa
niluu Omu-Ijẹbu.
No comments:
Post a Comment