Dele Mọmọdu lo sọrọ naa lori
ikani ayelujara ti Twitter laipẹ yi pe ki asiko to o lọ, ki Alaaji Atiku tete
pe Aarẹ Buhari nitori pe bi eto ikabo ṣe n lọ yi, o ti fi han daju pe Aarẹ
Buhari ti jawe olubori.
Gbajumọ akọroyin lorileede
Naijiria, Ọgbẹni Dele Mọmọdu ti parọwa si oludije sipo Aarẹ orileede yi labẹ asia
ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Alaaji Atiku Abubakar pe ko tete gbe
foonu ẹ lati ki Aarẹ Muhammadu Buhari ku oriire gẹgẹ bi Aarẹ ana, bi Dọkita Goodluck
Jonathan ṣe ṣe nigba ti ẹ, iyẹn lọdun 2015.
No comments:
Post a Comment