SUBEB PARI IDANWO IGBEGA FAWỌN OLUKỌ NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 26, 2019

SUBEB PARI IDANWO IGBEGA FAWỌN OLUKỌ NIPINLẸ OGUN

Lẹyin ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ti fi aṣẹ sii pe kawọn olukọ (non-teaching staff) kaakiri ipinlẹ naa bẹrẹ idanwo lati le gba igbega, ajọ to n sakoso eto ẹkọ, Universal Basic Education Board, ẹka tipinlẹ Ogun ti kede sita pe awọn ti pari idanwo fawọn eeyan naa.

Gẹgẹ b’AWIKONKO ṣe gbọ idanwo naa la gbọ pe awọn ti wọn ti perege fun igbega laarin ọdun 2016 si ọdun 2017 lawọn oluko ti wọn pari idanwo ati gbogbo eto fawọn ti ipo tuntun tọ si.

Yatọ si pe wọn peregede fun idanwo ti wọn ṣe fawọn to wa nipele kẹfa si ipele kẹwaa atawọn to wa nipele kejila soke ni wọn tun ṣe ifọrọwerọ pẹlu ti wọn si peregede.

AWIKONKO gbọ pe lara awọn idanwo tawọn eeyan naa ṣe ni ti imọ ẹrọ kọmputa (CBT), kikọ ati sisọ, olu ileeṣẹ ajọ SUBEB ni eto naa ti waye niluu Abẹokuta laipẹ yi.

Nigba to n dahun ibeere tawọn akọroyin n beere lọwọ ẹ, akọwe ajọ naa, Ọgbẹni Ọlalekan Kuyẹ fi idunnu ẹ han, o si gboriyin fun gomina Ibikunle Amosun fun igbesẹ tuntun naa.

Bẹẹ lo gbe oṣuba kare fawọn to ṣagbatẹru eto naa latile titi dopin, iyẹn Bureau of Establishments and Training, paapaa fun ifọwọsowọpọ wọn lakoko ti eto naa n lọ lọwọ.

Bakan naa, Ọgbẹni Adesoji Adewuyi to jẹ alakoso gbawọn oṣiṣẹ naa lamọnran pe ki wọn tubọ rii daju pe wọn sunmọ ẹrọ kọmputa daadaa, lati le tẹle awọn ilana ati ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI