Àjọ Tó Ń Sètò Ìdìbò Nilẹ̀ Wa,
INEC ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé mìmì kan ò lè mì nínú ètò ìdìbò tí
yóò wáye láìpẹ́ yìí ní ìpínlẹ̀ náà.
Olùdarí àjọ náà ní ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀gbẹ́ni
Mutiu Agbókè ló sípayá ọ̀rọ̀ yìí nibí ètò ìlanilọ́yẹ kan lórí ètò ìdìbò tó wáyé
láipẹ̀ yìí ní ìlú Ìbàdàn.
Ọ̀gbẹ́ni Agbókè ní ohun gbogbo ti
tò láti mú àyípadà tó lọ́rìn-ìn bá ìlànà àti ìgbésẹ̀ ìṣiṣẹ́ àjọ náà pàápàá ní
Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kí àyípadà tó hànde lè bá iṣẹ́ wọn.
Ó fi kún un pé àwọn ìgbésẹ̀ tí àjọ
náà ti gbé láti jẹ́ kí wọ́n ṣe àṣeyọrí ló wà lórí ètò àbò, ìpèsè àwọn ìwé ìdìbò
àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí bí ó ṣe yẹ kí àwọn olùdìbò lọ́nà tó yẹ ni.
Agbókè, ẹni tí Akọ̀wé fún Àjọ náà
ní Ìpínlẹ̀ náà, David Asemo ṣojú fún ṣàlàyé pé àwọn ti mú àyẹ̀wò káàdì ní ibùdó
ìdìbò tẹ̀wọ̀ síi ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, àwọn sì ti mú ìgbéru bá àwọn ẹ̀rọ ayẹkáàdìwò.
Ó tẹ̀síwájú pé àjọ náà kò sinmi
láti dá àwọn olùdìbò lẹ́kọ̀ọ́ lórí pàtàkì gbígba káàdì ìdìbò alálòpẹ́wọn àti bí
ó sẹ yẹ kí wọ́n ṣe tẹ̀ka sínú ìwé ìdìbò kí ìbò wọn máa báa já sófo.
Ó fi kún un gbogbo àjọ tó lóhun ṣe
lẹ́ka àbò ni àwọn ti ṣe ipadé pẹ̀lú tí àwọn sì ti fi oríkorí fikùnlukùn láti mú
àbò gbópọn pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn kò ni fi àyè sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni láti da ètò
ìdìbò náà rùú.
No comments:
Post a Comment