Ọ̀YỌ́ 2019: NBC GBA ÀWỌN ONÍRÒYÌN LÁMỌ̀RÀN LÓRI TÍTẸ̀LÉ ÌLÀNÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 10, 2019

Ọ̀YỌ́ 2019: NBC GBA ÀWỌN ONÍRÒYÌN LÁMỌ̀RÀN LÓRI TÍTẸ̀LÉ ÌLÀNÀ


Àjọ tó ń rí sí bí isẹ́ ìgbọ́hùnsáfẹ́fẹ́ ṣe ń lọ sí nilẹ̀ wa, National Boardcasting Commission (NBC) ti gba àwọn iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti àwọn iléeṣẹ́ ìwé-ìròyìn ní àmọ̀ràn láti mú iṣẹ́ wọn lókùńkúndùn kí wọ́n sì tẹ̀lẹ́ àwọn ìlànà tó rọ̀mọ́ ètò ìdìbò nínú ètò ìdìbò tó ń bọ̀,

Olùdarí ajọ náà fún ẹkùn iwọ̀ oòrùn, Ọlájùmọ̀kẹ́ Aya Ọgínni ló pe ipè yìí lọ́jọ́ Àìkú nigbà tó ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ níbi ìtakùsọ̀rọ̀ fún àwọn adíje sípò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ èyí tí ilé isẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, Fresh fm gbé kalẹ̀ ní ìlú Ìbàdàn.

Arábìnrin Ọlájùmọ̀kẹ́ Oginni ní ojúṣe àwọn oníròyìn ni láti máa gbé ìròyìn tí ó jẹ́ ògidì nítorí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ gùnlé ojúṣe wọ̀nyí nínú ètò ìdìbò tí yóò wáyé láìpẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó ní ojúṣe pàtàkì àwọn oníròyìn fún ètò ìdìbò náà ni láti gbé èsì ìdìbò tí Àjọ INEC nìkan bá fi síta láìyọ tàbí ṣe àfikún rẹ̀.

Ó rọ̀ wọ́n láti yẹra fún gbígbé ìròyìn tí ó lè fa rògbòdìyàn láwùjọ kí wọ́n sì má gbà olóṣèlú kankan láàyè láti sì wọn lọ́kàn.

Olùdarí ọ̀ún wá pé àwọn ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti oníròyìn sójúṣe wọn nípa mímọjútó àwọn oṣìṣẹ́ wọn lásìkò ìdìbò náà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI