Ọ̀YỌ́ 2019: Ẹ MÁ JẸ́ KÍ WỌ́N TÀN YÍN JẸ, ÀSÌKÒ TI TÓ FÚN ÀWA OBÌNRIN LÁTI DI GÓMÌNÀ – ALIYU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 2, 2019

Ọ̀YỌ́ 2019: Ẹ MÁ JẸ́ KÍ WỌ́N TÀN YÍN JẸ, ÀSÌKÒ TI TÓ FÚN ÀWA OBÌNRIN LÁTI DI GÓMÌNÀ – ALIYU



Ọmọbabìnrin Bọ́láńlé Sàrùmí Aliyu ti ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ kan lágbo òṣèlú pé àtàrí àjànàkú ni ẹrù ọṣẹ̀lú ilẹ̀ wa Nàíjíríà jẹ́ fún àwọn obìnrin lásìkò yìí gẹ́gẹ́ bí irọ́ tí kò sí òtítọ́ kankan nínú rẹ̀.

Bọ́láńlé Aliyu ló jẹ́ adíje sípò gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú National Interest Party (NIP) tí ó sì sọ̀rọ̀ yìí ní Ọjọ́ Etì ní ìlú Ìbàdàn níbi ìtàkùrọ̀sọ ìtagbangba tí iléeṣẹ́ BBCNEWSYORÙBÁ ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ fún àwọn adíjẹ sípò gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ó ní ọ̀nà àtifọ́wọ́ rọ́ àwọn obìnrin sẹ́yìn nínú òṣèlú ni lílo ọ̀rọ̀ náà jẹ́ pẹ̀lú àlàyé pé agbára àwọn obìnrin láti ṣe ìjọba ni àwọn olọ́ṣẹ̀lú ilẹ̀ yìí ti fojú parẹ́ tí wọ́n sì ti kà wọ́n sí olùrànlọ́wọ́ lásán.

Ó tẹ̀síwájú pé ipò tí ó ga ju nínú òṣèlú tí obìnrin lẹ̀ dèé ni igbákejì gómìnà èyí ti ó ń ṣàfihàn pé ètò òṣèlú ilẹ̀ wa kò tí i ṣéé mú yangàn tàbí fi wé ti àwọn ìlú mìíran tí wọ́n ti lọ́rúkọ lágbàyé.

Ọmọbabìnrin Aliyu ní àsìkò ti tó fún àwọn obìnrin láti dìde sí ìpèníjà yìí kí wọ́n ba lẹ̀ fi han gbogbo aráyé pé àwọn obìnrin ilẹ̀ wa ní ohun gbogbo lọ́wọ́ láti mu tẹrú-tọmọ jẹ ìgbádùn mùdùnmúdùn ètò ìjọba àwarawa tí wọ́n ti ń poǹgbẹ fún.

Nígbà tó wá ń pe àwọn obìnrin níjà láti gbọ́jú àgan sí ọ̀rọ̀ náà, Ọmọbabìnrin Aliyu ní ìdí nìyí tí òun fi gbégbá ìbò sí ipò gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti fi ẹ̀yìn ẹ̀tàn náà balẹ̀ kí omìnira dé bá àwọn obìnrin lágbo òṣèlú.

Ó wá ṣe ìlérí àtimú ìmáyégbádùn bá àwọn obìnrin pàápàá lẹ́ka ìlera, ètò ọmọ bíbí pẹ̀lú àfikún pé ìrónilágbárá àwọn ọ̀dọ́ ló jẹ́ ẹ lógún bí ó bá dépò náà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI