Ọla Eyitayọ,
Ọyọ
Iyalẹnu lọrọ awọn ọmọ Yahoo tọwọ awọn ajọ EFCC tẹ laipẹ yi niluu Ibadan latari bi wọn ṣe ba oriṣiriṣi oogun abẹnugọngọ, ọṣẹ dudu atawọn mọto bọginni-bọginni.
Agbegbe Ologunẹru ati Akobọ nillu Ibadan la gbọ pe ọwọ ti tẹ awọn
mọkandinlogun naa.
Awọn naa ni Bamidele Ayọdele Samson, Bamidele Philip, Tunji Ọladapọ
Ṣowale, Bọlaji Ọlalekan, Abdulrauf Abiọdun, Ọlalẹyẹ Pẹlumi, Anuoluwapọ
Ọlanrewaju, Paul Damilọla, Ọlalẹyẹ David Tobi, Arẹwa Adekunle Ibrahim, Oyesanmi
Ayọmikun Oluwaṣeun, Ọlalẹyẹ Israel, Adediran Kemisọla, Ọmọbọlade Alarape ati
Olowolusi Oluwatomisin.
Awọn to ku ni Babatunde Afeez, Akorede Ahmed Ọlalekan, Adelẹyẹ Damilọla ati
Moshood Richard.
AWIKONKO gbọ pe laarin ọdun mọkanlelogun si ọdun marundinlogoji lawọn
gendekunrin naa tọwọ tẹ yi, akẹkọọ wa lara wọn bẹẹ lawọn kan ti jade ile ẹkọ.
No comments:
Post a Comment