Ọga ọlọpaa patapata lorileede Naijiria, Mohammed Adamu ti fi ọrọ sita pe gbogbo oṣiṣẹ ọlọpaa ti ko ba lo taagi gẹgẹ bi aami idanimọ lasiko idibo to n bọ lọna lọjọ Satide Ọtunla yoo fẹnu fẹra bi abẹbẹ, nitori pe igi oyin lo ru.
Eyi lọ nibamu pẹlu ofin tuntun
ti wọn ṣe fun eto idibo, lati le jẹ ki eto naa lọ nirọwọ irọsẹ, lai si wahala
kankan.
O lawọn ọlọpaa ti wọn ba pin
sawọn agbegbe ti idibo yoo ti waye ni wọn gbọdọ fi aami idanmọ, iyẹn taagi
sọrun wọn lati le mọ awọn to ba jẹ ojulowo yatọ sawọn ayederu ọlọpaa.
Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ
pe bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ti yoo ṣiṣẹ lawọn agbegbe ti idibo yoo ti waye
lọjọ naa, ṣugbọn sibẹ, wọn yoo lo irinṣẹ mamugaari, iyẹn handcuffs lọjọ naa.
Bẹẹ lo tun sọ pe gbogbo awọn
ọlọpaa naa gbọdọ ti de awọn agbegbe ti wọn pin si laago marun aarọ ki eto too
bẹrẹ rara, lati le fimu finlẹ daadaa.
No comments:
Post a Comment