ÒKÚ SALA NI WỌ́N RÍ GBÉ NÍNÚ BÀÁLÙ TÓ JÁ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 8, 2019

ÒKÚ SALA NI WỌ́N RÍ GBÉ NÍNÚ BÀÁLÙ TÓ JÁ

Àwọn ikọ̀ tó kóra wọn jọ láti ṣàwárí ọkọ̀ òfurufú tó gbé agbábọ́ọ̀lù tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Cardiff City rà, ti fidìí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọkù Emiliano Sala ni àwọn rí nínú àfọ́kù okọ̀ òfurufú tó gbé láti Orílẹ̀ Èdè France wá sí pápá ìṣeré ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà.

Atẹ̀jáde kan tí wọ́n gbé jáde lọ́jọ́ Ẹtì, ṣàláyé pé ìwádìí wọn fihàn pé òkú Sala ni wọ́n rí gbé láti inú ọkọ̀ òfurufú náà tí wọ́n sì ti fi tó àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ létí.

Wọ́n ní ojú ọjọ́ tí ò dára jẹ́ ipèníjà wọn lẹ́yìí tí wọn kò sì lè tètè ṣe àwárí ọkọ̀ òfurufú náà ṣùgbọ́n pẹ̀lú irànlọ́wọ́ àwọn ẹ̀rọ awẹ̀kún ti igbàlódé tí wọ́n lò, igbìyànjú wọn já si ire.

Ọjọ́ Ajé ni wọ́n kẹ́fín okú agbábọ́ọ̀lù ọmọ ọdún méjìdínlógún náà tí wọ́n sì mú iṣẹ́ ṣe láti yó ó kúrò nínú àfọ́kù ọkọ̀ òfurufú náà pẹ̀lú ọkọ̀ awẹ̀kun, Geo Ocean III, tí wọ́n sì ṣe àṣeyọrí rẹ̀ lọ́jọ́bọ̀.

Ní kété tí èsì ìwádìí yìí jáde ni Ẹgbẹ́ Cardiff City ti bá mọ̀lẹ́bí agbábọ́ọ̀lù náà kẹ́dùn tí wọ́n sì ṣàpèjúwe bí ikú Sala ṣe dùn wọ́n sí nínú atẹ̀jáde tí wọ́n fi síta.
Bákan náà ni àbúrò olóògbé náà, Romina pòréré ikú ẹgbọ́n rẹ̀ lórí ìkannì rẹ̀ lórí Instagram.

Orísirísi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ni àwọn ènìyàn ti ń fi ránṣẹ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára pàápàá jùlọ àwọn agbábọ́ọ̀lù ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó fi mọ́ Antonio Rudiger ti Ikọ̀ Chelsea, Mesut Ozil ti Arsenal àti Lionel Messi ti Barcelona, ẹni tí ó ti ṣíṣe àwári náà lọ́wọ́ pẹ̀lú owó tó gbé kalẹ̀.

   

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI