Lẹyin ọpọlọpọ wahala to sẹlẹ
lori Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Ahmed Iliyasu ti wọn gbe kuro nipinlẹ Ogun, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede pe
Kọmiṣana mẹrin ọtọọtọ ni yoo ṣakoso idibo Aarẹ ti yoo waye ni ọla Satide.
Awọn Kọmiṣana naa ni Yẹmi
Agunbiade ti yoo ṣoju Ogun East; Fimihan Adeoye ti yoo ṣakoso Ogun West; Gbenga
Adeyanju ti yoo ṣakoso Ogun Central ati AIG Shehu Lawal toun jẹ olori wọn
patapata.
Yatọ si pe wọn yan awọn eeyan
yi, bẹẹ nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tun fi awọn ẹrọ ibanisọrọ sita, fawọn araalu
lati pe wọn si akiyesi eyikeyi ti wọn ba ri ladugbo wọn lakoko idibo.
1. AIG Shehu Lawal - 08033560903
Ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ Ogun
2. CP Gbenga Adeyanju - 08055051818
fun Ogun Central.
3. CP Fimihan Adeoye 08033415589
fun Ogun West.
4. CP Yemi Agunbiade 08034506364
fun Ogun East.
No comments:
Post a Comment