Ẹsẹ ko gbero ninu ọfiisi Ọga agba ẹgbẹ Fijilante tipinlẹ Ogun, iyẹn Fijilante Service of Ogun State, VSO, Ọgbẹni Sọji Ganzallo lọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi nibi ayẹyẹ ọjọ ibi to ṣe, tawọn oṣiṣẹ si fi imọriri mọ si ọga wọn.
Bi orin ọlọkan-o-jọkan ṣe lọ naa ni adura ko gbẹyin fun Ọgbẹni Sọji Ganzallo, tawọn eeyan tun fi ẹbun oriṣiriṣ ta ọkunrin naa l'ọrẹ, bẹẹ ni akara oyinbo tun n pe ara wọn niṣẹ.
Wọnyi ni diẹ lara awọn fọto ayẹyẹ rampẹ naa.
Sọji Ganzallo nigba to n fẹmi imoore han, o dupẹ lọwọ Ọlọrun, paapaa awọn alatilẹyin ẹ nidi iṣẹ naa, bẹẹ lo gboriyin fun bi wọn ti n gbaruku ti saa ẹ gẹgẹ bi ọga agba ẹgbẹ Fijilante naa.
No comments:
Post a Comment