ỌBANIKORO N FI ẸWỌN ṢERE – ILE ẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 7, 2019

ỌBANIKORO N FI ẸWỌN ṢERE – ILE ẸJỌ

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta

Ile ẹjọ to n gbọ ẹsun ti wọn fi kan gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Ayọdele Fayọṣe ti pariwo sita pe bi ẹlẹri ajọ EFCC, Musiliu Ọbanikoro ko ba tete wa a yọju si kọọtu ko too pẹ ju, ẹwọn lo fi n ṣere.

Ajọ to n gbojunti iwa ajẹbanu, Economic and Financial Cirme Commission, EFCC lo fẹsun jibiti owo ti ko din ni biliọnu meji naira kan Ayọdele Fayọṣe, ti Musiliu Ọbanikoro si jẹri tako Fayọṣe lọjọ Tusde to kọja yi.

Oni Tọside lo yẹ ki Ọbanikoro tun pada yọju si kọọtu lati tẹsiwaju nipa sisọ ohun to mọ nipa ẹsun ti ajọ EFCC fi kan Fayọṣe, ṣugbọ iyalẹnu lo jẹ pe esi ti wọn ri gba lati ọdọ Ọbanikoro ni pe ara ẹ ko ya, osibitu lo si wa, nibi ti wọn da a duro sii.

Nigba to n sọ fun ile ẹjọ naa, agbẹjọro ajọ EFCC, Rotimi Jacobs (SAN) jẹ ko ye ile ẹjọ pe iyalẹnu lo jẹ foun pe Ọbanikoro to wa ni kọọ nijẹta, tii ṣe Tuside,  lẹta loun ri gba lati ọdọ Ọbanikoro pe ara ẹ ko ya, ati pe o tun fi iwe ọsibitu to wa lagbegbe Ikoyi ranṣẹ.

Onidajọ naa, Mojisọla Ọlatoregun pẹlu ibinu lo fi sọrọ pe boun ba fi le ṣe iwadii daadaa, toun si rii pe ayederu niwe naa jẹ, o ni ati ọsibitu ati Ọbanikoro funra ẹ, ẹwọn ni wọn fi n ṣere.

Nigba to n sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun yi, Onidajọ Mojisọla sọ pe bi Ọbanikoro ba kọ lati yọju ki igbẹjọ to o bẹrẹ, afaimọ ko ba jẹ pe yoo ṣẹwọn oṣu meta, ko si jẹ pe mọto ti wọn fi n gbe awọn ẹlewọn, iyẹn Black Maria ni wọn yoo maa fi gbe e wa si kọọtu nigbogbo igba ti igbẹjọ ba n waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI