Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Afaimọ ko ma jẹ pe inu
ibẹrubojo lawọn Aarẹ tẹlẹri lorileede yi yoo ti dibo to n bọ yi, latari bi ọga
ologun orileede yi, Jẹnẹra Tukur Buratai ṣe paṣẹ pe ki gbogbo awọn ọmọ ogun ti
wọn wa lẹyin awọn agbaagba lorileede Naijiria kuro lẹyin wọn.
Bo tilẹ jẹ pe Buratai sọ pe kii
ṣe pe Aarẹ Muhammadu Buhari lo paṣẹ naa ninu ipade to ṣe pẹlu awọn eleto aabo
patapata, ṣugbọn funra oun loun paṣẹ naa latari bi ko ṣe nii si igbokegbodo
lasiko idibo.
Buratai wa a paṣẹ fawọn adari
ologun kaakiri pe ki wọn fiya jẹ gbogbo ẹni tọwọ ba tẹ pe o n huwa ti ko tọ
lasiko idibo.
No comments:
Post a Comment