Lẹyin ti wọn yọ Ọlamiju Alao Akala, to jẹ ọmọ gomina ana nipinlẹ Ọyọ kuro nipo gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ ariwa Ogbomoṣọ, iyẹn Ogbomoso Noirth, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣebura fun igbakeji rẹ, Abass Bello Bayewuwọn gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ naa.
Kọmiṣọna fun amojuto ijọba
ibilẹ ati oye jijẹ, Bimbọ Kọlade lo ṣeto ibura naa nileeṣẹ ijọba ibilẹ Ogbomọṣọ
North.
N ṣe ni awọn agbofinro pọ babi
si ayika ileeṣẹ ijọba ibilẹ naa, gẹgẹ bii awọn tisẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe sọ.
Laipẹ yii ni awọn kansilọ mẹrin
ninu mẹwa to wa ni ijọba ibilẹ naa, dibo yọ Ọlamiju lẹyin to kede pe oun n fi
ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ si ẹgbẹ oṣelu ADP, nibi ti baba rẹ ti n gbe igba dije
fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ.
Ni owurọ ọjọru ni gomina tẹlẹ
nipinlẹ Ọyọ, Adebayọ Alao Akala ṣi n fi to ileeṣẹ BBC news Yoruba leti pe, iwa
kotọ ti ko lee duro niwaju ofin ni yiyọ ti wọn yọ ọmọ oun nipo ati pe, oun ṣi
ni alaga ijọba ibilẹ Ogbomọṣọ North.
- BBC
No comments:
Post a Comment