Ajọ eleto idibo orileede yi, INEC ti kede sita laarọ kutu oni pe idibo apapọ to yẹ ko waye lonii Satide Abamẹta pe ko nii waye mọ, dipo bẹẹ, ọjọ Satide tii ṣe ọjọ kẹtalelogun ni idibọ naa yoo tun pada waye.
AWIKONKO gbọ pe kii ṣe pe ajọ
INEC dee de sun idibo naa siwaju, bi ko ṣe pe lati le jẹ kidibo naa lọ bo ṣe yẹ ko lọ, paapaa awọn iroyin kan to tẹ wọn lọwọ pe awọn
kan ti ṣetan lati dabaru idibo naa, paapaa bawọn ẹgbẹ oṣelu kan ti ṣe gbaradi
lati ji apoti ibo gbe.
Ajọ INEC sọ pe idibo Aarẹ ati
ti Sẹnetọ, to fi mọ tawọn aṣoju-ṣofin yoo waye lọjọ kẹalelogun, iyẹn Satide ọsẹ
to n bọ, nigba ti idibo Gomina to yẹ ko waye lọjọ keji oṣu kẹta yoo waye lọjọ
kẹsan an oṣu kẹta.
Nigba to n kede iroyin nipa
ayipada naa, ọga agba fun ajọ naa, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu laago mẹta ku iṣẹju
mẹwaa (2:50am), o rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiri ti wọn ti gbaradi lati dibo, bẹẹ
ni ko faaye silẹ fun ibeere kankan.
Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe “Ajọ
eleto idibo, Independent National Electoral Commission ṣepade lọjọ Fraide ana
lati tun agbeyẹwo idibo to yẹ ko waye lọjọ Satide onii ati Satide kinni ninu
oṣu keta ọdun yi.
“Ni titẹle awọn amuyẹ lati jẹ
ki idibo naa lọ nirọwọ irọsẹ, ajọ naa pinu lati sun idibo siwaju, paapaa latari
awọn nnkan to le di wọn lọwọ ninu igbaradi naa.”
No comments:
Post a Comment