Iná
náà èyí tí wọn kò mọ bí ó ṣe sẹ́yọ ni ó bẹ̀rẹ̀ ní ọwọ́ aago márùn-ún fẹ̀ẹ̀rẹ̀
ní àsìkò tí àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ń sùn lọ́wọ́ tí ó sì ṣe ikú pa agbábọ́ọ̀lù mẹ́wàá
tí àwọn mẹ́ta mìíràn sì farapa.
Gẹ́gẹ́
bí àwọn olóri ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà ṣe sọ, àwọn agbábọ́ọ̀lù náà tí wọ́n bá ìsẹ̀lẹ̀
náà lọ ni ọjọ́ orí wọn wà láàárín mẹ́rìnlá àti mẹ́tàdínlógún tí àwọn mẹ́ta tí wọ́n
farapa náà ti ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn kan.
Gómìnà
ìpínlẹ̀ Rio de Janeiro, Wilson Witzel ti kéde ọjọ́ mẹ́ta láti fi ṣọ̀fọ̀ àwọn tí
wọ́n bá ìjàmbá náà lọ.
No comments:
Post a Comment