O DA MI LOJU PE ATIKU YOO BORI - ṢẸGUN ṢOWUNMI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 23, 2019

O DA MI LOJU PE ATIKU YOO BORI - ṢẸGUN ṢOWUNMI

Oludije sipo ile igbimọ aṣọfin kekere niluu Abuja labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọmọba Ṣẹgun Ṣowunmi ti fọwọ sọya pe o da oun loju pe oludije sipo Aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ naa, Alaaji Atiku Abubakar ni yoo bori ninu idibo to n lọ lọwọ yi, iyẹn lasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

Ọmọba Ṣẹgun Ṣowunmi lo fidi ọrọ naa mulẹ lasiko to n b'AWIKONKO sọrọ ni wọọdu to ti dibo lagbegbe Itoko niluu Abẹokuta lonii.

O sọ pe, pẹlu awọn nnkan toun ri lawọn ibi ti idibo ti waye kaakiri agbegbe toun ṣabẹwo si, ati wọọdu toun ti dibo, o ni ko si nnkan to fẹẹ jẹ ibẹru foun nitori pe ọrọ iṣejọba APC ti su araalu, ti wọn si n fẹ ayipada rere.

Ṣẹgun Ṣowunmi to fẹẹ lọ ọ ṣoju awọn ara Abẹokuta South nile igbimọ aṣoju-ṣofin kekere niluu Abuja ni igbẹkẹle toun ni ninu awọn oludibo, ati ọrọ tawọn araalu n sọ ti fi han daju pe Atiku ni yoo bori.

Siwaju sii lo tun jẹ ko di mimọ pe ọkan oun balẹ pe awọnm eeyan jade dupo daadaa lati dibo yan awọn ti yoo sin wọn fun ọdun mẹrin min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI