NJẸ Ẹ TI GBỌ: ṢỌỌṢI MFM TUN GBE IKEDE SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 18, 2019

NJẸ Ẹ TI GBỌ: ṢỌỌṢI MFM TUN GBE IKEDE SITA


Ṣọọṣi Ori Oke Ina ati Iṣẹ Iyanu, iyẹn Mountain of Fire and Miracles Ministries (MFM) ti kede sita pe ipade adura oloṣooṣu wọn to maa n waye ni gbogbo ọjọ Satide akọkọ ninu oṣu, eyi ti wọn ti sọ pe ọjọ kẹsan an ninu oṣu kẹta ni yoo waye tẹlẹ ti yi pada bayii.

Gẹgẹ bi ikede ti ṣọọṣi naa ṣe lori ẹrọ ayelujara wọn laipẹ yi ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ọjọ Satide akọkọ ti wọn maa ṣe tẹlẹ naa ni yoo pada waye.

Bẹ o ba gbagbe, lọjọ keji oṣu yi la mu iroyin naa wa fun un yin pe latari idibo gomina ti ajọ eleto idibo, iyẹn INEC sọ pe yoo waye lọjọ keji oṣu kẹta, to jẹ ọjọ ti ipade adura Agbara Gbọdọ Paarọ Ọwọ naa maa n waye, idi ni yii ti oludasilẹ ṣọọṣi naa, Dọkita Kọlawole Olukọya fi kede pe ipade adura naa ko nii waye bo ṣe n maa n waye loṣu kẹta ọdun yi.


Dọkita Olukọya sọ pe Satide keji, tii ṣe ọjọ kẹsan an oṣu kẹta ni yoo waye, to si mu kawọn ọmọ ṣọọṣi naa maa gbaradi fun ọjọ naa.

Ni bayii, pẹlu ikede naa, latari bi ajọ INEC ti ṣe sọ pe awọn ti sun ibo gomina si ọjọ kẹsan an oṣu kẹta, igbimọ alakoso ṣọọṣi naa ti sọ pe Satide akọkọ ti ipade naa maa n waye ni yoo pada waye, nitori naa awọn ko sun un siwaju mọ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI