Latari idibo
apapọ orileede yi ti wọn loo lọ nirọwọ-irọsẹ nipinlẹ Ekiti, Gomina ipinlẹ naa,
Dọkitọ Kayọde Fayẹmi ti gba ṣọọṣi lọ lati lọọ ṣe akanṣe idupẹ.
Nibẹ lo ti
dupẹ gidigidi lọwọ Ọlọrun atawọn araalu fun ifọwọsowọpọ wọn fun ti idibo to
waye naa, paapaa bi awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa ṣe gba alaafia laaye lasiko
idibo.
Ṣọọṣi ile ijọba
to wa niluu Ado-Akiti, iyẹn Goverment House Chapel ni Gomina Fayẹmi ti lewaju
awọn bii Ọmọba Dayọ Adeyẹye ti wọn ṣẹṣẹ yan fun ipo Sẹnetọ aarin gbungbun
Ekiti; Ọnọrebu Ṣọla Fatọba, ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa,
ati Ọjọgbọn Dupẹ Adelabu toun ti figba kan ri jẹ igbakeji gomina.
No comments:
Post a Comment