Ọjọ́ Iṣẹ́gun tó kọjá ni Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Nantes
kọ̀wé láti bẹ̀rẹ̀ owó tí wọ́n ta agbábọ́ọ̀lù náà fún Cardiff ṣùgbọ́n tí ikọ̀
náà kò i tí fi owó náà ránṣẹ́.
Ọjọ́
mẹ́je síi ni Cardiff ní láti san Mílíọ́nù mẹ́ẹ̀dọ́gún owó Yúrò tí wọ́n bá Ikọ̀
Nantes ní adéjùn rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wọn tọwọ́ bọ̀wé lásìkò tí wọ́n ń ṣe
ìdúnàádúrà pẹ̀lú wọn.
Gẹ́gẹ́
bí Nantes ṣe kọ́ sínú ìwé tí wọ́n fi ṣọwọ́ sí Cardiff, ọwọ́ òfin ni wọn yóò fi
mú ọ̀rọ̀ náà bí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà bá kùnà láti san owó náà èyí tíi ṣe abala
àkọ́kọ́ nínú owó tí wọ́n bá wọn ní àdéhùn rẹ̀ láàárin ọjó mẹ́je òní.
Wọ́n
ní bí Cardiff bá kò láti mú àdéhùn ṣẹ, àwọn yóò wọ́ wọn lọ iwájú àjọ tó ń rí sí
rírà àti títa agbábọ́ọ̀lù lábẹ́ Àjọ FIFA àti àjọ tó ń rí sí ìdíje Premier League.
Nínú
èsì wọn, Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Cardiff City ní ìgbésè Nantes náà jọ wọ́n lójú gan-an
nítorí pé lásìkò tí ikọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ owó lọ́wọ́ wọn jẹ́ ìgbà tí ìgbésẹ̀ ṣíṣe
àwárí agbábọ́ọ̀lù náà ń lọ lọ́wọ́.
Wọ́n
ní òótọ́ ni àwọn mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn san owó náà ṣùgbọ́n yóò wù wọ́n kí Nantes
mú sùúrù di ìgbà tí gbogbo ìwádìí lórí ikú agbábọ́ọ̀lù náà yóò fi wá sọpin.
Wọ́n
fi kún un pé àìtètè san owó náà ni àwọn fi ń bọlá fún mọ̀lẹ́bí Emiliano Sala tí
àwọn sì ń dúró dìgbà tí wọ́n parí wíwá àgbábọ́ọ̀lù náà.
Bí ọ̀rọ̀
bá bẹ́yìn yọ fún Cardiff, wọn yóò pàdánù àmì díẹ̀ nínú èyí tí wọ́n ní lórí tábílí
ìdíje ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀sì tí wọ́n wà.
Lọ́wọ́lọ́wọ́,
òkú Emiliano Sala ni wọ́n kéde pé wọ́n rí gbé nínú àfọ́kù ọkọ̀ òfurufú tó gbé e
láti France èyí tó já sínú òkun.
No comments:
Post a Comment