Ọla Eyitayọ, Ọyọ
Bi ajọ eleto idibo ṣe kede
Ọmọwe Kọla Balogun pe oun lo jawe olubori nibi idibo awọn aṣofin agba niluu
Abuja, eyi to waye niluu Ibadan lọjọ Satide to kọja yi, loju ẹsẹ ni Gomina
Abiọla Ajimọbi ti bu sẹkun bi ọmọ tuntun jojolo.
Ṣugbọn ṣa, ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ ti kọwe ẹhonu si ajọ eleto idibo orileede Naijiria, INEC, nipa awọn aiṣedeede ti wọn loo jẹyọ lasiko eto idibo sile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja lẹkun guusu ipinlẹ Ọyọ.
Ẹgbẹ oṣelu APC ṣalaye pe, awọn
aiṣedeede naa lo ṣokunfa bi Gomina Abiọla Ajimọbi ṣe fidirẹmi ninu ibo naa, ti
wọn si ti fi iwe ẹhonu naa pẹlu abọ iwadi awọn ọlọpaa silẹ fun ajọ INEC.
Ọmọwe Azeez Ọlatunde, to jẹ
oludari fun eto iwadi ati aato fẹgbẹ APC, lo gbe iwe ẹhonu naa kalẹ lọjọ Aje
onii, lẹyin ti ajọ INEC kede Ọmọwe Kọla Balogun pe oun lo bori ninu ibo sile igbimọ
aṣofin agba naa.
Ṣaaju asiko yi ni Ọmọwe Azeez
Ọlatunde, tii ṣe aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ni ibudo ti wọn ti n ka ibo awọn aṣofin
agba naa, ti kọkọ fapa janu ni ibudo ti wọn ti n ka ibo naa pe, wọn ko gbọdọ
kede esi ibo ọhun.
Ọlatunde ni awọn janduku kan lo
wa a da ibo ru ni wọọdu mẹta kan lẹkun idibo ọhun, eyi to mu ki awọn ibo ti wọn
padanu pọ pupọ.
Ṣugbọn oṣisẹ ajọ eleto idibo,
to n ṣe kokaari esi ibo naa, Ọjọgbọn Wọle Akinsọla ni ki aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC
ko gbogbo ẹhonu to ba ni lọ si olu ileeṣẹ ajọ eleto idibo, to si kede esi ibo
naa.
Ọmọwe Kọla Balogun si lo jawe
olubori ninu ibo naa, ti Senetọ Abiọla Ajimọbi si se ipo keji.
Ohun tawọn kan n sọ bayii ni pe
kin ni Gomina Ajimọbi tun n wa kaakiri lẹyin to ti figba kan ri sọ ọ nita
gbangba pe oun ko tun nilo ipo kankan mọ lẹyin Gomina ẹlẹẹkeji ti wọn foun
lanfaani ẹ yi.
No comments:
Post a Comment