Àwọn
àgbà wòólì kan tí wọ́n fi ìlú Ìbàdàn ṣe ìbujọ́kọ̀ọ́ ti fọwọ́ sòyà pé ètò ìdìbò
tó ń bọ̀ lọ́nà yóò lọ ní ìwọ́rọ́-ìwọṣẹ̀ pàápàá ètò ìdìbò ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bí àwọn ọmọ Nàíjíríà bá lè di
ìgbàgbọ́ wọ́n nínú Ọlọ́run mú sinsin.
Wòólì Michael Òjó Ọlọ́wẹrẹ́ tí gbogbo ènìyàn mọ̀
sí “Bàbá automatic”, Àpọ̀stélì Sam Pópóọlá àti àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn ló fi
ìdánilójú yìí hàn ní Ọjọ́ Àbámẹ́ta àná níbi ìpàdé akànṣe àdúrà kan èyí tí aya
gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gbékalẹ̀ fún àwọn obìnrin ní papa ìṣeré Lékan Sàlámì.
Àgbà Wòólì
nì, Wòólì Ọlọ́wẹ́rẹ́ ẹni tó sọ̀rọ̀ àṣẹ̀ pé agbára okùnkùn kan kò lè borí
Nàíjíríà, ṣàlàyé pé ọpẹ́ ló yẹ kí àwọn ọmọ Nàíjíríà máa dá fún Ọlọ́run tí Ó gba
iṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ láàyè ní orílẹ̀-èdè yìí bí ó ti wù kí làásìgbò tí àwọn ẹni
ibi dá sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè yìí pọ̀ tó.
Ó wá
pe àwọn ọmọ ilẹ̀ yìí níjà láti kọ́ bí a ṣe yin Ọlọ́run nígbà gbogbo pẹ̀lú
àfikún pé Ọlọ́run mọ rírì yíyìn Ín nígbà gbogbo.
Ní tirẹ̀,
Àpọ̀stélì Pópóọlá, ẹni tí i ṣe Alákoso Àgbà fún ìjọ World Communication
Ministry sọ̀rọ̀ aṣẹ̀ pé orílẹ̀-èdè Nàíjírà kò ní ní ìrírí wàhálà tàbí rògbòdìyàn
kankan lásìkò ìdìbò náà.
Ó ní “gbogbo
ikọ̀ òkùnkùn tí ń ṣiṣẹ́ tọ rògbòdìyàn nínú ètò ìdìbò tó ń bọ̀ ni iná yóò jó run.
Gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run ni yóò fi ẹ̀mi ṣọ̀kan láti mu àláfíà jọba nílẹ̀ yìí”.
Nígbà
tó ń sọ̀rọ̀, Aya Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Florence Aya Ajímọ̀bi gba àwọn òbí lámọ́ràn
láti ki àwọn ọmọ nílọ̀ lórí ewu tó wà nínú lílọ́wọ́ sí jàgídíjàga kí wọ́n sì rántí
pé àwọn olóṣèlú tí ń lò wọ́n fi àwọn ọmọ wọn pa mọ́ tí wọn kò sì lò wọ́n fún
ìwa burúkú lásìkò ìdìbò.
Ó ní òun
ní ìdánilójú pé gbogbo ọmọ oyè lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress
(APC) ló máa jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà pàápàá ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nítorí àṣeyọrí
ti ọkọ òun ti ṣe nínú ṣáà méjèèjì tọ́kọ òun lò lórí oyè.
Gbogbo
àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó wà níbi ètò náà ni Bíṣọ̀bù D.S. Ọláníyì, Olùsọ́ágùntàn Dọlápọ̀
Adélakùn, Ajíhìnrere Toun Ṣóẹ̀tán, Ajíhìnrerebìnrin Kẹ́mi Ọ̀pátúndé, Olùsọ́àgùntàn
Deborah Ayọ̀kúnlé, Ajíhìnrere Bùkọ́lá Akinadé, Comfort Aya Akínfẹ́nwá àti àwọn
mìíràn.
No comments:
Post a Comment