Àsà àti ìṣe BBC ni láti máa fún gbogbo ènìyàn ní pèpéle kan náà, ìdí niyìí tí wọ́n ṣe ti ṣáájú kọ̀wé pe gbogbo àwọn olùdíje sípò gómìnà tí àwọn ènìyàn sọ pé àwọn ń fẹ́ láti rí níbi ìpàdé ìtagbangba ìpínlẹ̀ Ogun. ẹgbẹ́ òṣèlú méje la gbọ pe BBC fiwe pè.
PDP: Buruji Kashamu
APM: Adekunle Akinlade
ANN: Ademola Ogunbanjọ
ADP: Dimeji Bankole
APC: Dapo Abiodun
ADC: Gboyega Nasiru Isiaka
SDP: Rotimi Paseda
Àwọn olùdíje mẹ́ta ló kọ̀ tí kò wá tí wọn kò sì
kọ̀wé ránṣẹ́ pé àwọn kò ni wá, àwọn olùdíje náà ni Dimeji Bankole ti ẹgbẹ́
òṣèlú ADP, Dapo Abiodun ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti Buruji Kashamu ti ẹgbẹ́ òṣèlú
PDP lẹ́yin ti wọn ti sọ pé àwọn yóò yọjú.
Nínú àwọn olùdíje ti kò yọju yìí sí fi dá ilé iṣẹ́
BBC lóju titi dí alẹ ọjọ́bọ̀ pé àwọn ń bọ sùgbọn titi tí ìròyìn yìí fí ń jáde à
kò ti gbọ́ ìdí ti wọn kò fi péjú síbẹ̀
Ẹwẹ, gbogbo awọn oludije to yọju lo wu awọn eniyan
lori pẹlu gbogbo alakalẹ aato wọn lọlọkan o jọkan ti wọn ni awọn yoo gbe ṣe bi
awọn ba di gomina ipinlẹ Ogun.
- BBC
No comments:
Post a Comment