Mínísítà fún Ètò Ìròyìn àti Àṣà
nílẹ̀ wa, Alhaji Lai Muhammed ló fi èyí síta nínú àtẹ̀jáde kan fún àwọn
oníròyìn, nínú èyí tí ó pe ìròyìn náà ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́.
Ó ní àhésọ lásán ni èyí tí àwọn ẹgbẹ́
alátakò gbẹ́ jáde láti ba ìjọba tó wà lóde lórúkọ jẹ́ pàápàá lásìkò tí ètò
ìdìbò ń bọ́.
Ó ní ọ̀nà mìíràn rèé tí àwọn alátakò
fẹ́ fi sọ Àarẹ Muhammadu Buhari lórúkọ burúkú kí àwọn ará ìlú lẹ̀ rí i gẹ́gẹ́
bí ẹni tí kò nání àláfíà àwọn ará ìlú tí ó sì dágunlá sí ìgbáyégbádùn wọn.
Ó wá rò àwọn ará ìlú láti gbè lẹ́yìn
Àarẹ Buhari nítorí òun nìkan ni ọmọ oyè tí ó nífẹ̀ẹ́ ọmọ Nàíjíríà.
No comments:
Post a Comment