INÚ VICTOR MOSES DÙN GAN-AN NI LÓRÍ ÀMÌ ÀYÒ ÀKỌ́KỌ́ RẸ̀ TÓ GBÁ WỌLÉ FÚN FENERBACHE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 2, 2019

INÚ VICTOR MOSES DÙN GAN-AN NI LÓRÍ ÀMÌ ÀYÒ ÀKỌ́KỌ́ RẸ̀ TÓ GBÁ WỌLÉ FÚN FENERBACHE

Victor Moses

Bí ènìyàn bá gun ẹsin kọjá nínú Victor Moses lọ́jọ́ Ẹtì, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní kọsẹ̀ láéláé nítorí bí inú rẹ̀ ṣe dùn tó lórí góòlù akọ́kọ́ rẹ̀ tí ó gbá wọlé fún Ikọ̀ Fenerbache.

Victor Moses, ẹni tí wọ́n fi rọ́pọ̀ Andre Ayew, ló kó ipa ribiribi nínú ìjáwéolúborí wọn nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tí wọ́n gbá pẹ̀lú ikọ̀ Goztepe.

Góòlù àkọ́kọ́ rẹ̀ yìí ló jẹ́ àmì ayò kejì tí Ikọ̀ Fenerbache fi borí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn náà èyí tí ó mu u bọ́ sórí ìkànnì ayélujá rẹ̀ lórí Twitter láti yàyọ̀ yìí pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, Ikọ̀ Fenerbache ti bọ́ sí ipò kọkànlá lórí tábílì ìdíje Turkish Super League tí wọ́n wà pẹ̀lú àmì mẹ́tàdínlógún nínú ìfẹ̀sẹ̀wọnsẹ̀ ogún tí wọ́n ti gbá.

Victor Moses ní ìrètí láti bá ikọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ìfésẹ̀wọnsẹ̀ ti wọ́n ní lópin ọ̀ṣẹ̀ tó ń bọ̀ èyí tí yóò si mú u kúrò lóri àga ìpaàrọ̀.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI