Adíje
sípò àarẹ ilẹ̀ wa kan lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democractic Party (PDP), Atiku
Abubakar ti fi ìdùnnú rẹ̀ hàn lórí bí Ọlọ́run ṣe kó Ìgbákejì Àaré ilẹ̀ wa, Ọjọ̀gbọ́n
Yẹmí Ọ̀sínbàjò yọ nínú ijàmba ọkọ́ òfurufú hẹlikọ́pítà tó sẹlẹ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.
Ọjọ́
Àbámẹ́ta tí ìsẹ̀lẹ̀ náà sẹlẹ̀ ni ìròyìn ti kan Atiku lára tí ó sì gba ìkannì
ayélujára rẹ̀ lórí Twitter lọ lọ́jọ́ Àìkú láti kí Ìgbákejì Àaré náà kú ẹwu.
Ó ní
òun bá Ọ̀sínbàjò yọ̀ pé àláfíà ara ni òun àti àwọn ikọ̀ tí wọ́n tẹ̀le e wà.
Bákan
náà ni ìròyìn tọ́ ń tẹ Awíkonko lọ́wọ́ ṣàlàyé pé tìdùnnú-tìdùnnú ni Ọ̀jọ́gbọ́n
Yẹmí Ọ̀sínbàjò fi lọ sílé ìjọsìn lọ́jọ́ Àìkú láti fọpẹ́ fỌ́lọ́run fún dídá ẹ̀mí
rẹ̀ sí.
Ìdúpẹ́
pàtàkì náà ló wáyé ní ilé ìjọsìn Redeemed Christian Church of God (RCCG), City
of Grace tó wà ní Lokoja níbi tí Olùsọ́àgùntàn Àgbà fún ilé ìjọsìn náà, Olùsọ́àgùntàn
Enoch Adébóyè ti bá Ìgbákejì Àarẹ wa fi àdúrà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run àbò naà.
No comments:
Post a Comment