IJỌBA IRỌ GOMINA AMOSUN TI SU WA - ẸGBẸ AWỌN OṢIṢẸ FẸYINTI PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 28, 2019

IJỌBA IRỌ GOMINA AMOSUN TI SU WA - ẸGBẸ AWỌN OṢIṢẸ FẸYINTI PARIWO SITA

Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta 

Apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fẹyinti, Nigeria Union of Pensioners (NUP), ẹka tipinlẹ Ogun ti bu ẹnu atẹ lu ijọba Gomina ipinlẹ naa, Ibikunle Amosun pe ijọba irọ lo kun ‘bẹ.

Wọn sọrọ naa lasiko ti wọn n gba oludije sipo Gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọba Dapọ Abiọdun nibi ipade ẹgbẹ wọn ti wọn maa n ṣe loṣooṣu, eyi ti wọn ṣe niluu Abẹokuta.

Nibi ipade naa ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ọna kan ṣoṣo tawọn le fi bọ ninu ijọba ileri ori ahọn ti Gomina Amosun n ṣe ni ki Ọmọba Dapọ Abiọdun wọle gẹgẹ bi Gomina ninu idibo to n bọ lọjọ Satide, ọjọ kẹsan an, oṣu kẹta.

Nigba to n sọrọ, alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Kessington Oduwọle sọ pe lati kekere ni Ọmọba Dapọ Abiọdun ti jẹ ọrẹ timọtimọ oun, toun si nigbagbọ pe yoo ṣe daadaa ju ti ijọba to wa nita yi lọ, nitori pe baba ẹ naa wa lara awọn oṣiṣẹ fẹyinti.

Ṣaaju asiko yi, akọwe ẹgbẹ naa, Kọmureedi Bọla Lawal sọ nipa iya ajẹkudorogbo to n jẹ awọn oṣiṣẹ fẹyinti nipinlẹ Ogun ninu ijọba Gomina Amosun, to si ni o ti su awọn.

O ni lati ọdun 2013 ni Gomina Amosun ti jẹ awọn lowo oṣu ajẹẹlẹ ati owo ifẹyinti wọn, atawọn ẹtọ to tọ si wọn.

Ninu ọrọ tiẹ, Gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba to tẹle Ọmọba Dapọ Abiọdun lọ banujẹ gidigidi lori ọrọ tẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fẹyinti sọ pe o ti le lọdun mẹfa ti Gomina Amosun ti jẹ wọn lowo, o si fọkan wọn balẹ pe irọrun ni ọrọ wọn yoo ja si bi adije naa ba wọle.

Nigba toun naa n dupẹ lọwọ wọn fun bi wọn ṣe gba a laaye, o fọkan wọn balẹ pe gbogbo ẹtọ to ba tọ si wọn loun ko nii fi iya ẹ jẹ wọn boun ba de ipo naa, o wa a gba wọn lamọnran pe ki wọn jade sita dibo basiko ba de.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI