Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Iyalẹnu lọrọ naa ṣi n jẹ fawọn
eeyan nigba ti wọn gbọ wi pe asọtẹlẹ ọkan lara awọn gbajumọ Wolii lorileede
Naijiria, iyẹn Wolii TB Joshua ni nnkan bi ọjọ meloo kan sẹyin wi pe eto idibo
ko ni i waye loni-in Satide, ọjọ kẹrindinlogun oṣu yii gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe fi han
oun.
Ni nnkan bi ọjọ meloo kan sẹyin
ni gbajugbaja Wolii agbaye naa, TB
Joshua sọ wi pe, ti ajọ INEC ko ba mura daadaa, o ṣee ṣe ki eto idibo ma waye
loni-in gege bi ajọ ọhun ṣe la a kalẹ.
Lasiko ti Wolii ijọ Synagogue
of All Nations, eyi to wa ni lagbegbe Ikotun niluu Ekoo n ṣe waasu fun awọn ọmọ
ijọ ẹ lo fi wọn lọkan balẹ wi pe wahala kan bayii ko ni i ṣẹlẹ lori idibo ni Naijiria,
ṣugbọn bi Ọlọrun ṣe fi han oun, ibo ko ni i waye lọjọ ti ajọ INEC kede e, ati pe
ohun ti yoo fa a ko ni i se lẹyin awọn kudiẹ-kudiẹ kọọkan to maa waye.
Ninu ọrọ ẹ lọjọ naa lo ti sọ pe
“Ibo ta a fe di ni Naijiria lọjọ kẹrindinlogun yẹn, o ṣee ṣe ki o ma waye
latari awọn kudiẹ-kudiẹ kọọkan to maa waye, ṣugbọn mo nigbagbọ wi pe agbara Ọlọrun
yoo ka a.”
Bo ṣe sọrọ ọhun niyẹn o, nigba
to si ku dẹdẹ loootọ ki eto ibo waye loni-in, nni ajọ naa atawọn ti ọrọ kan ba
wọle ijiroro lati ọwọ irọlẹ ana Fraide ọjọ kẹẹdogun, nigba ti wọn yoo si pari
ipade, nibẹ gan-an ni wọn ti sọ pe ibo ko ni i le waye mọ loni-in, o di Satide
to n bọ, nitori awọn gbọdọ mura silẹ fun un daadaa, ki ibo naa le kẹsẹjari.
Ṣa o, Ọgbẹni Yakubu Muhammed, ẹni
ti i ṣe olori ajọ naa ti sọ pe orinkinniwin alaye lori ohun to mu awọn taari
ibo ọhun siwaju lawọn yoo pe ipade awọn oniroyin lee lori ni deede aago meji ọsan
oni.
- Magasinni Alore
No comments:
Post a Comment