IDIBO KU ỌJỌ MEJI, ALAGA ẸGBẸ OṢELU PDP F'ẸGBẸ SILẸ, LO BA DARAPỌ MỌ APC LATI ṢATILẸYIN FUN BUHARI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 22, 2019

IDIBO KU ỌJỌ MEJI, ALAGA ẸGBẸ OṢELU PDP F'ẸGBẸ SILẸ, LO BA DARAPỌ MỌ APC LATI ṢATILẸYIN FUN BUHARI

Ojiji lọrọ naa de ba gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP patapata nipinlẹ Yobe nigba ti wọn gbọ pe alaga wọn f'ẹgbẹ silẹ lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lati ṣatilẹyin fun Aarẹ Muhammadu Buhari ninu idibo to n bọ lọjọ Satide ọla.

Bo tilẹ jẹ pe wọn loo ti pẹ ti ẹgbẹ oṣelu APC ti n pe alaga naa, Alaaji Sani Inuwa Nguru pe ko wa a ṣiṣẹ fawọn, ti wọn si tun ṣeleri owo yanturu fun un, ṣugbọn to n sọ pe ko si nnkan to le gbe oun kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Kayeefi lọrọ naa jẹ fun gbogbo eeyan lọjọ Tọside ana nigba ti adari ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, Dọkita Mohammed Abuza wọ Nguru lọ sọdọ Aarẹ Muhammadu Buhari, to si f'ọkan wọn balẹ pe oun yoo ṣiṣẹ fun wọn lọjọ Satide ọla yi.

Fawọn to ba mọ bi oṣelu ipinlẹ Benue ṣe n lọ, Alaaji Nguru ni alaga akọkọ f'ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Yobe ko too di pe o darapọ mọ PDP nigba t'awọn wahala kan ṣẹlẹ nibẹ.

Latigba to si ti darapọ mọ PDP ni wọn ti n bẹbẹ pe ko pada sinu ẹgbẹ APC nitori ti wọn mọ ipa to ko nigba to fi jẹ alaga.

Ni bayii, AWIKONKO gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ko tii mọ ọna ti wọn fẹ ẹ gbe idibo naa gba lati rii pe adije sipo Aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Atiku Abubakar wọle nipinlẹ naa, paapaa nigba ti wọn sọ pe lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP naa ti tẹle Nguru lọ APC.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI