IBO KU DẸDẸ, WỌN JI OLORI AWỌN OBINRIN LẸGBẸ OṢELU APC NIPINLẸ DELTA GBE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 16, 2019

IBO KU DẸDẸ, WỌN JI OLORI AWỌN OBINRIN LẸGBẸ OṢELU APC NIPINLẸ DELTA GBE

Lasiko ti ipalẹmọ ipolongo idibo n kasẹ nilẹ la gbọ pe awọn agbebọn kan ti ko tii sẹni to mọ wọn titi ta a fi ṣakojọpọ iroyin yi tan ji olori awọn obinrin fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Delta gbe.

Obinrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Margaret, ẹni aadọta ọdun la gbọ pe wọn ji gbe loju ọna ibi ti wọn ti n bọ lati ibi ipolongo idibo ti wọn ṣe lagbegbe Orogun, nijọba ibilẹ Ughelli North lọjọ Tọside to koja yi, ta a si gbọ pe wọn ti n beere miliọnu lọna ọgbọn ki wọn to le fi silẹ.

A gbọ pe awọn mẹrin ni wọn wa ninu mọto lasiko tawọn ajinigbe da wọn duro, ṣugbọn tawọn mẹta raaye salọ fun wọn, ti ori si tako obinrin toun naa ti figba kan ri gbe apoti kasẹlọ ri.

Wọn ni ọkan lara awọn to n ṣailẹyin fun Sẹnetọ Ovie Ọmọ- Agege to n ṣoju Aarin gbungbun ipinlẹ Delta (Delta Central Senetorial District) ni Margaret, ọmọ agbegbe Efunrun nijọba ibilẹ Uvwie ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI