Atiku ni, ori oun wu nigba ti
awọn ọmọ Naijiria fi kaadi idibo wọn yọ Aarẹ ana, Goodluck Ebele Jonathan lasiko
idibo to waye ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 2015.
O ni, "Awa eniyan Naijiria
lọ si ibi idibo pẹlu kaadi idibo wa nikan, a si yọ olori orilẹede yii nigba
naa. Oun to jẹ ki ori mi wu niyẹn gẹgẹbii ọmọ Naijiria. Ni ọsẹ yii, a o ni
anfani lati ṣe bẹẹ lẹẹkan si."
Atiku tẹsiwaju, o ni eni yoowu
ti awọn ọmọ Naijiria ba fẹ dibo fun, ki wọn gbiyanju lati jade dibo lọjọ
Abamẹta.
O ni ni ọjọ idibo, ibo kan ko
lagbara ju omiran lọ.
- BBC
No comments:
Post a Comment