Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
Orin ọpẹ lawọn ara agbegbe ti ko din ni metadinlogoji (37
Communities) nipinlẹ Ekiti mu sẹnu lonii ọjọ kẹrin oṣu keji ọdun 2019 nigba ti
Gomina ipinlẹ naa, Dọkita Kayọde Fayẹmi fun wọn niwe sọwedowo to fi diẹ din
nigba (194.3m) miliọnu naira lati fi mu idagbasoke bawọn agbegbe wọn.
Owo naa la gbọ pe ajọ to n mu idagbasoke bawọn agbegbe
lagbaye ti banki agbaye ṣagbatẹru ẹ, lo gbe owo naa silẹ lati fi pari awọn akanṣe
iṣẹ apati kaakiri ipinlẹ naa.
Owo naa la tun gbọ pe wọn ti gbe kalẹ ni saa akọkọ iṣejọba
Gomina Fayẹmi, ṣugbọn ti Gomina ana, Ayọdele Fayọṣe ko pari ẹ titi to fi kuro
nijọba, ati pe gẹgẹ bi ijọba toun to n gbọ igbe araalu, oun ko nii gba ki iṣẹ
naa ma tẹ siwaju.
Gomina Fayẹmi nigba to n sọrọ sọ pe oun ti ni kawọn
agbaṣẹṣe pada sẹnu iṣẹ lati tẹsiwaju awọn ọna ti wọn ti pati.
Nigba to n gba ẹnu awọn araalu dupẹ lọwọ Gomina Fayẹmi, Ọba
Gabriel Adejuwọn, Onisan tiluu Isan ni awọn mọ pe ijọba Gomina yoo so eso rere,
nitori naa lawọn ṣe gbọdọ maa gbe oṣuba kare fun un.
No comments:
Post a Comment