Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Pẹlu idunnu ati ayọ lawọn ti
wọn ti di ipo oṣelu mu lẹka ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Ogun fi gba owo to tọ si
wọn gẹgẹ bi owo ifẹyinti lonii ọjọ Wẹside, ni gbagede tawọn ologun to wa ni
Oke-Mọsan niluu Abẹokuta.
Awọn ti wọn ti dipo oṣelu ijọba
ibilẹ mu laarin ọdun 2007 si ọdun 2010 la gbọ pe wọn gba owo naa, wọn to fi
mẹfa din ni l’Ẹgbẹrin (793) lawọn ti wọn jẹ anfaani owo yi, lẹsẹkẹsẹ ni Gomina
Amosun ti fun wọn niwe sowe-dowo wọn.
AWIKONKO gbọ pe biliọnu meji
aabọ (2.5b) naira lowo tawọn eeyan naa gba, bẹẹ la si gbọ pe awọn ti wọn dipo
oṣelu nijọba ipinlẹ laarin ọdun 2007 si ọdun 2015 naa gba ninu owo yi pẹluu
A gbọ pe ọdun 2014 ni Gomina
Amosun bẹrẹ eto naa, nigba to fawọn to wa nipele akọkọ lowo, to si tun tẹsiwaju
pẹlu ipeleke keji lọdun 2016, ko too di onii to fawọn to wa nipele kẹta lowo ti
wọn.
No comments:
Post a Comment