Ninu esi rẹ, o dupẹ lọdọ ara
ipinlẹ Ọyọ ṣugbọn ko ki akẹgbẹ rẹ to jawe olubori ku oriire aṣeyọri rẹ.
Ikini yi la ri ninu fọnran
fidio kan ti o ti sọ fun oniroyin Dele Momodu pe inu ohun dun si bi ibo naa ti
ṣe lọ.
Ẹka ẹrọ ayelujara ti Instagram
ni fọnran naa wa nibi ti Gomina Ajimobi ti dupẹ lọwọ Ọlọrun fun anfaani ti ohun
ni lati sin awọn eeyan ipinlẹ Oyo.
O ka awọn aṣeyọri rẹ lori idibo
to n lọ lọwọ ti o si ni ohun ko ipa ribi ribi lati ri wi pe ipinlẹ Ọyọ dibo fun
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ẹgbẹ oṣelu APC.
Toun ti bi o ti ṣe ni inu ohun
dun ga an lori ibo naa, oni ohun ko ni i ki akẹgbẹ ohun to jawe olubori aya fii
ti ohun ba ri aridaju pe ko si mago-mago ninu idibo.
APC Oyo ti saaju fapá jánú lórì
ìfìdírẹmi Ajimọbi.
Ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ọyọ ti
kọwe ẹhonu si ajọ eleto idibo nilẹ wa, INEC, nipa awọn aisedeede to sọ pe o
suyọ lasiko eto idibo sile asofin agba lẹkun guusu ipinlẹ Ọyọ.
Ẹgbẹ oselu APC salaye pe, awọn
aisedeede naa lo sokunfa bi gomina Abiola Ajimọbi se fidirẹmi ninu ibo naa, ti
wọn si ti fi iwe ẹhonu naa pẹlu abọ iwadi awọn ọlọpa silẹ fun ajọ INEC.
Ọmọwe Azeez Ọlatunde, tii se
oludari fun eto iwadi ati aato fẹgbẹ APC, lo gbe iwe ẹhonu naa kalẹ lọjọ Aje,
lẹyin ti ajọ INEC kede Ọmọwe Kọla Balogun pe oun lo bori ninu ibo sile asofin
agba naa.
Saaju ni Ọmọwe Azeez Ọlatunde ,
tii se asoju ẹgbẹ oselu APC ni ibudo ti wọn ti n ka ibo sile asofin agba naa,
ti kọkọ fapa janu ni ibudo ti wọn ti n ka ibo naa pe, wọn ko gbọdọ kede esi ibo
ọhun.
Ọlatunde ni awọn janduku kan lo
wa da ibo ru ni wọọdu mẹta kan lẹkun idibo ọhun, eyi to mu ki awọn ibo ti wọn
padanu pọ pupọ.
Sugbọn osisẹ ajọ eleto idibo,
to n se kokari esi ibo naa, Ọjọgbọn Wọle Akinsọla ni ki asoju ẹgbẹ oselu APC ko
gbogbo ẹhonu to ba ni lọ si olu ileesẹ ajọ eleto idibo, to si kede esi ibo naa.
Ọmọwe Kọla Balogun si lo jawe
olubori ninu ibo naa, ti Senetọ Abiọla Ajimọbi si se ipo keji.
No comments:
Post a Comment