EYI NI BI WỌN ṢE FẸẸ BA TI ỌṢINBAJO JẸ PATAPATA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 21, 2019

EYI NI BI WỌN ṢE FẸẸ BA TI ỌṢINBAJO JẸ PATAPATA

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun 

Latari ahesọ kan to n lọ kaakiri ori ẹrọ ayelujara pe Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ti kọwe fipo silẹ gẹgẹbi igbakeji Aarẹ orileede Naijiria, Ọṣinbajo funra ẹ ti pariwo sita pe ko si nnkan to jọ iroyin naa rara, o ni iroyin ẹlẹjẹ lasan ni.

Ọṣinbajo lo fidi ọrọ naa mulẹ lori ẹka ayelujara ti Twitter rẹ wipe, ayederu iroyin ti wọpọ ni orilẹede Nigeria nitori oṣelu.

O ni “Iroyin to n ṣi awọn eeyan lọkan lo pọ ju lasiko yi, nigba ti awọn ọmọ Naijiria fẹẹ pinu ẹni ti yoo dari wọn fun ọdun mẹrin min in to n bọ.

“Mi o ti i kọwe fipo silẹ o. Mo duro digbi lati ṣiṣẹ sin awọn ọmọ Naijiria labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari.

A gbọ wipe awọn iroyin ofege naa sọ wipe, Osinbajo ti fi ibinu kọwe fipo silẹ nitori wipe wọn ko pe e si ibi ipade kan to waye nile ijọba laipẹ yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI