ÈYÍ NI BÁWỌN TỌ́Ọ̀GÌ PDP ṢE YA BO ÌPOLONGO ADÉLABÚ NÍ IGBÓ-ỌRÀ, Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN LÓ FARAPA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 3, 2019

ÈYÍ NI BÁWỌN TỌ́Ọ̀GÌ PDP ṢE YA BO ÌPOLONGO ADÉLABÚ NÍ IGBÓ-ỌRÀ, Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN LÓ FARAPA

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ìlú Ìgbó-ọrà pàápàá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) ló farapa yánayàna nígbà tí àwọn kan tí wọ́n tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí tọ́ọ̀gì ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ṣe kọlu wọ́n níbi ìpolongo tí adíje sípò gómìnà lábẹ́ òṣèlú APC, Olóyè Adébáyọ̀ Adélabú ṣe níbẹ̀.

Ní kété tí Olóyè Adélabú àti Gómìnà Abíọ́lá Ajímọbì ti bá àwọn alátìlẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú náà sọ̀rọ̀ níbi ìpolongo ọ̀ún ni àwọn jàǹdùkú náà náà tú jáde láti inú ìbuba wọ́n tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí máa kọlu wọ́n pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà olóró.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tọ́rọ̀ náà ṣe ojú wọn ṣe sọ, ó gba àwọn oṣìṣẹ́ elétò àbò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà láti mú adíje sípò gómìnà náà, Adélabú kúrò níbi rògbòdìyàn náà.

Wọ́n ṣàlàyé pé kòju ìṣẹ̀jú díè tí wọ́n rí Adélabú gbé kúrò níbẹ̀ ni àwọn tọ́ọ̀gì ọ̀ún tú kẹ̀kẹ́ ìjà wọn sílẹ̀, tí wọ́n sì ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lẹ́se.

Lẹ́yìn èyí ni àwọn jàǹdùkú náà wá bẹ̀rẹ̀ sí ní yìbọn sókè kíkọnkíkọn tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní dúkokò mọ́ ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí pẹ̀lú aṣọ tàbí ohun tó níi ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Inúfu àyàfu ni àwọn aráàlú Igbó-Ọrà wà lẹ́yìn tí rògbòdìyàn náà ti wáyé.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI