Adíje
sípò gómìnà kan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Adébáyọ̀ Adélabú ti ṣàpàjúwe ètò òṣèlú ilẹ̀
wa Nàíríjíà gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò ṣéé mú yangàn láàárin àwọn ìlú olókìkí mìíràn
lágbàyé.
Adélabú,
ẹni tó jẹ́ adíjẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), ló ṣàpèjúwé
òṣèlú Nàíjíríà gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò buyì kún ètò ìjọba àwarawa níbi ìtakùrọ̀sọ
ìtagbangba tí iléesẹ́ BBCNEWSYORÙBÁ sètò rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì.
Ó ní
ìwà ipá àti jàgídíjàgan ni àwọn olóṣèlú ilẹ̀ wa mú wọ ètò òṣèlú èyí tí kò fún ìṣejọba
àwarawa ní ìtumọ̀ tó mọ́yánlórí bẹ́ẹ̀ sì ni kò mú u gùnkè àgbà.
Ó tẹ̀síwájú
pé ilẹ̀ wa nìkan ni lílo bàbá ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú ti wọ́pọ̀ jùlọ tí kò sì fi àyè
gba àwọn tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará ìlú láti ṣe ìjọba.
Ó wá
fi dá àwọn ènìyàn lójú pé òun yóò sa gbogbo ipa òun láti fi ayé dẹ ará ìlú lọ́rùn
pàápàá lẹ́tò ìlera, ìrónilágbara àti ètò àbò.
No comments:
Post a Comment