Alaga ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, SDP lorileede Naijiria, Oloye Olu Falae ti pariwo sita pe oun ko kọwe fipo kankan silẹ, depodepo pe oun fi oṣelu silẹ patapata, o ni ahesọ lasan niroyin ti wọn gbe kaakiri.
Oloye Falae lo fidi ọrọ naa
mulẹ fun akọroyin PUNCH lọsan onii niluu Akurẹ, o jẹ ko di mimọ pe lootọ loun
fẹyin ti lati maa da si gbogbo oṣelu to n lọ lorileede yi, ṣugbọn ko kọwe fipo
silẹ gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ oṣelu SDP.
Ninu ọrọ ẹ, o sọ pe “Mo kan
pinu lati fẹyinti fun bi mo ṣe n da si ọrọ oṣelu lorileede yi nigba ti mo pe
ọmọ ọgọrin (80) ọdun. Oṣu kẹsan an ọdun to kọja ni mo pe ọgọrin ọdun, mo fẹ ẹ
kede ifẹyinti mi lọjọ naa, ṣugbọn ipade gbogboogbo ẹgbẹ ti sunmọ etile, lẹyin
igba naa ni Ọjọgbọn Jerry Gana gbe wa lọ si kọọtu, idi ni yi ti mi o fi kede.
“Fun idi eyi, pẹlu ilana ẹgbẹ,
Ọjọgbọ Tunde Adeniran ni alaga fidihẹ lapapọ bayii, mo ti fẹyinti, ṣugbọn mi o
kọwe fipo naa silẹ.”
No comments:
Post a Comment