Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi ti pariwo sita pe k'awọn to n gbe ayederu iroyin kaakiri pe oun wa nibi ipade ikọkọ ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ṣe pẹlu awọn oloṣelu laipẹ yi tete paarẹ, ati pe latari bi wọn yoo ṣe ṣeto ibo to n bọ yi nipade naa wa fun.
Lọsan onii niroyin naa jade sori ẹrọ ayelujara, nigba ti iroyin Nigerian Cable News gbe iroyin naa pe Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ to jẹ Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria wa nibi ipade ikọkọ pẹlu awọn oloṣelu kan bii alaga ẹgbẹ oṣelu ADP, Oloye Wale Egunleti, adije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, Ọmọba Gboyega Isiaka.
Awọn min in ta a gbọ pe wọn tun wa nibi ipade ikọkọ naa ni Ọmọba Jide Ojuko to jẹ adari ẹka ẹgbẹ oṣelu APM, Ọgbẹni Ayọ Olubori to jẹ akọwe fidihẹ lẹgbẹ oṣelu APC, to fi mọ alukoro ọlọpaa, Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi toun ṣoju ileeṣẹ ọlọpaa.
Inu ọfiisi Ọbasanjọ to wa nile ikawe Aarẹ, iyẹn Ọbasanjọ Presidential Library ni iroyin naa sọ pe wọn ti ṣe ipade ikọkọ naa lọsan onii.
Nigba to n fesi si iroyin naa, Oyeyẹmi sọ pe irọ nla to jinna si otitọ ọrọ patapata ni iroyin naa, nitori pe oun ko gbọ nipa ipade kankan pẹlu Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, depodepo pe oun yoo wa nibe.
Oyeyẹmi sọ pe eyi to ti ẹ jẹ koko ni pe, oun ko si niluu Abeokuta lonii, ti ko si ṣee ṣe foun lati wa nibi ipade ti wọn sọ, ati pe bi eeyan ba fẹ ẹ ṣoju ileeṣẹ ọlọpaa, kii ṣe oun nitori toun tun lawọn ọga niwaju, ti wọn le wa nibi ipade naa.
O wa a rọ ẹni to ko iroyin naa pe ko tete paarẹ kuro lori ẹrọ ayelujara ko too pẹ ju, k'awọn oniroyin si too bẹrẹ sii gbe kaakiri.
AWIKONKO gbọ pe o ṣee ṣe ki ileeṣẹ ọlọpaa fẹsun kan ileeṣẹ iroyin naa nile ẹjọ bi wọn ko ba tete gbe igbesẹ lati pa iroyin naa rẹ.
No comments:
Post a Comment