Ṣoworẹ to tun jẹ oludasile iwe iroyin ori ayelujara, Sahara Reporters ni ki awọn ọmọ Naijiria
ma gbaradi nitori ijọba pasan ni wọn dibo fun ti gbogbo wọn yoo si ni ipin ninu
rẹ.
Soworẹ salaye ọrọ yi wa nigba
to n ba BBC Yoruba sọrọ lori akanṣe eto nipa idibo aarẹ Naijiria.
''Ibo yi ko bojumu.Ti ẹ ba wo
daada, ẹ o ri wi pe awọn eeyan ko tuyaya jade paapa julọ nilu Eko lati dọwọ
idunnu esi ibo''
Sowore tẹsiwaju pe, pupo eeyan
ni ko ri bi dibo latari kọnukọhọ to wa ninu eto idibo naa.
O si da ẹbi aijade dibo daada
awọn ara ilu ru ọrọ ihalẹ ti aarẹ Buhari sọ saaju idibo.
Iṣoro ko ni si fun ọdọ mọ lọjọ
iwaju
Sowore dupe lọwọ awọn ọmọ
Naijiria to gbaruku ti ẹgbẹ rẹ ti wọn fi ṣe ipo kẹta ninu ibo naa.
O ni bayi ti awọn ti ri ipa ti
awọn oludije ọdo ko,iṣoro ko ni si lọjọ iwaaju fun awọn ọdọ lati de ipo oṣelu.
''Asiko ọ̀dọ́ ni ọdun mẹrin to
n bọ lọna.''
Sowore wa pe fun atunto eto
oṣelu ki o ba le jẹ ki awọn ọmọ Naijiria laanfaani lati kopa daada.
Nigba ti atọkun eto beere lọwọ
rẹ pe, ki ni yoo ṣe, to ba jẹ oun lo wole gẹgẹ bi Buhari? Sowore ni kiakia
lohun yoo yan awọn ti yoo ṣe ijọba ti awọn ko si ni dawọ iṣejọba duro.
''O ti wa lori oye tẹlẹ, ko si
yẹ ki idiwọ kankan waye lati maa tẹsiwaju pẹlu iṣejọba. Ọsẹ kan pere ni mo ma
fikede Minisita tuntun, ka ni emi ni Buhari."
- BBC
No comments:
Post a Comment