Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ
laipẹ yi ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe afaimọ ki ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ekiti ma
padanu ibo ọdun 2019 to n bọ yi sọwọ ẹgbẹ alatako wọn, iyẹn ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ohun ta a gbọ ni pe awọn kan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa, paapaa awọn to tun jẹ oloye ninu ẹgbẹ naa ṣiṣẹ labẹlẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP, ati pe lara awọn ti wọn
yan lati ṣabojuto eto idibo ipinlẹ naa n ji awọn owo to n wọle ko, ti wọn ko si
fi jiṣẹ sawọn ibi to yẹ ki wọn fi jiṣẹ si, ta a si gbọ pe ọpọ igba lawọn
agbaagba ẹgbẹ oṣelu naa ti kilọ fun wọn.
Lọjọ Fraide ana ni igbakeji
gomina ipinlẹ Ekiti, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi gbawọn eeyan naa lamọnran pe ki wọn ye
e fi ifẹ ọkan wọn ṣiṣẹ fun ẹgbẹ, bi ko ṣe pe ki wọn maa lo agbekalẹ ẹgbẹ lati
fi tukọ oṣelu, ki wọn ma baa padanu.
Ẹgbẹyẹmi to sọrọ yi lasiko ti
wọn gbe ọpa asṣẹ fawọn igbimọ ti wọn yan lati dari eto idibo laaringbungbun
ipinle Ekiti, iyẹn Ekiti Centra Senetorial campaign.
Igbakeji gomina naa tun sọ pe
oun mọ pe awọn kan ninu ẹgbẹ naa ṣetan lati dalẹ ẹgbẹ, kiru awọn bẹẹ si tete fi
ẹgbẹ silẹ ko too pẹ ju bi wọn ba mọ pe awọn ko le ṣiṣẹ gidi fẹgbẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, nigba toun naa n
sọrọ, alaga ẹgbẹ oṣelu naa nipinle Ekiti, Ọgbẹni Paul Ọmọtọṣọ gbawọn oloye
tuntun naa lamọnran pe ki wọn tubọ maa ṣe idanilẹkọọ fawọn olodibo to wa
lagbegbe wọn, ki wọn le mọ awọn nnkan to ba yẹ nipa idibo to wọle tan yi, lati
le dẹkun awọn ibo to maa n ṣofo danu.
O ni ninu idibo gomina to kọja
lọ, ko din lẹgbẹrun mejidinlogun ibo tawọn padanu latari ailoye to fawọn
oludibo, ati pe wọn ko dibo naa daadaa bo ṣe yẹ ki wọn di (void votes), to mu ki
aaye kekere ṣi silẹ lati bori.
Bakan naa lo tun sọ pe ẹni to
ba n gbiyanju lati dalẹ ẹgbẹ naa nipa lilo awọn ohun elo ẹgbẹ fi ṣiṣẹ ara ẹ,
iru ẹni bẹẹ yoo fi oṣelu pitan lorileede yi, paapaa bi wọn ba jẹ ki ẹgbẹ oṣelu
PDP rọwọ mu, nitori pe awọn ko nii gba fun ẹgbẹ PDP lati rọwọ, ati pe kawọn ọmọ
ẹgbẹ bọwọ fun ẹgbẹ naa.
Bakan naa lo tun sọ pe ẹgbẹ
oṣelu PDP ko ni aaye kankan mọ nipinlẹ naa, nitori naa, ọmọ ẹgbẹ oṣelu to ba
dalẹ ẹgbẹ yoo fẹnu fẹra bi abẹbẹ.
No comments:
Post a Comment