Bọsun Ọlaniyi, Abeokuta
Adije sipo ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin agba to fẹẹ lo ṣoju awọn ara agbegbe Abẹokuta North, Ọbafẹmi-Owode ati Ọdẹda, Amofin (Arabinrin) Abimbọla Lanre-Balogun ti sọ pe ko si ẹgbẹ oṣelu to le mu ayipada tawọn araalu n fẹ de ba orileede Naijiria, bi ko ṣe ẹgbẹ oṣelu PDP. Amofin Lanre-Balogun sọrọ yi nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu akọroyin AWIKONKO lopin ọsẹ to kọja yi niluu Abẹokuta, nibi to ti erongba ẹ lati jade dupo aṣoju-ṣofin ninu idibo to n bọ lọna yi. Ẹ ka bi ifọrọwerọ naa ṣe lọ.
Bi mo ṣe jẹ
Orukọ mi ni Amofin (Arabinrin) Abimbọla Lanre-Balogun, ti mo n dije dupo ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin ti ẹkun
Abẹokuta North/Ọbafẹmi-Owode ati Ọdẹda labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP. Ọmọ bibi ilu
Abẹokuta, lagbegbe Oke-Itoku ni mi, ko pẹ ti lasiko ti mo n dagba ni iṣẹ gbe
Baba mi lọ siluu Eko, ibẹ ni mo ti lọ sileewe alakọbẹrẹ, iyẹn Salvation Army,
mo tun lọ sileewe girama Girls College ni Bariga, fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ nibi
ti mo ti kẹkọọ nipa ofin.
Idi ti mo fi wọnu oṣelu
Oloṣelu ni baba mi, lasiko
ijọba lọdun 1999 ni mo ṣakiyesi pe awọn ti wọn ṣoju wa, paapaa julọ nijọba
ibilẹ Ọbafẹmi Owode ko kun oju oṣuwọn, wọn ko dara to fun wa, mo wa a sọ fun
baba mi pe emi naa fẹẹ darapọ oṣelu. Baba mi kilọ fun mi nigba naa, ṣugbọn mo
jẹ ko ye wọn pe a ko kan le jokoo, ka maa pariwo pe a n fẹ ayipada, a fi ka
jade sita, wọn si ni ko buru, idi ni yii ti mo fi darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu lọdun
2001. Ẹgbẹ oṣelu AD ni mo fi bẹrẹ, latigba naa ni mo ti n jade kaakiri lati
dasi eto oṣelu wa. Kii ṣe pe mo deede darapọ naa, ṣugbọn mo rii pe a ko kan le
laju silẹ ka jẹkawọn ti ko dara to lọ maa ṣe ofin to maa de wa, eyi to tunmọ si
pe kawọn oponu maa dari awọn ọlọgbọn, ko yẹ ko ri bẹẹ.
Awọn nnkan ti mo fẹẹ ko yipada gẹgẹ mi Amofin ti mo ba
wọle
Mo ni awọn nnkan mẹta kan
gboogi to n jẹ mi logun ninu ọkan mi fawọn eeyan, latigba ti mo si ti n jade
polongo idibo, mo ṣakiyesi pe awọn eeyan ta ma lọ n ba sọrọ la o ki n pada lọọ
ba nigba ti a ba wọle, ti a ko si n ṣe nnkan ti a ba ṣeleri fun wọn, wọn kii jẹ
mudun-mudun ijọba bii ọna gidi, eto ilera to peye, omi to ṣe e mu abbl., ko da
to fi mọ ileewe to dara, ileewe ijọba ni mo lọ, mo si mọ bo ṣe ri nigba naa, mo
si mọ awọn nnkan ti mo n ri bayii ti mo ba ṣabẹwo sabule, o maa n ba mi ninu jẹ
pupọ, mo wa a rii pe awọn ti wọn ti n ṣoju wa latẹyinwa gan an ko nimọ ẹkọ nipa
ofin, o wa a jẹ nnkan to ṣoro lati dari awọn eeyan sibi to yẹ, nitori pe nnkan
pataki ti wọn yan wọn fun ni lati gbe ofin kale fawọn eeyan ati ijọba. O kan jẹ
pe ofin ilẹ wa ko faaye silẹ pe ẹni to ba maa di ipo yi mu gbọdọ jẹ amofin. O si
maa n mu ọkan mi balẹ pe mo n lọ sori papa ti mo mọ daju pe mo peregede lati
lewaju, nitori pe mo mọ awọn nnkan to tọ lati ṣe, lati rii pe a gbe ofin ijọba
gidi kale.
O dami loju pe maa bori awọn alatako mi
Ọkan mi balẹ gidi pe mo baa
fẹyin awọn alatako mi gbolẹ, nitori pe laipẹ yi lawọn to n sabẹwo nipa idibo
nilẹ Europe (European Union of Election Monitoring Team) wa pẹlu mi lati mọ
oṣwọn ti mo gbe lati bori. Ẹ jẹ ki n tu aṣiri yi fun un yin, emi nikan ni adije
lẹgbẹ oṣelu PDP to jẹ obinrin, laarin awọn ogoji. Inu wọn dun lati ri mi, wọn
si fẹẹ tẹle mi lọ si ọkan lara awọn ipolongo ti mo n ṣe sawọn wọọdu kaakiri. A ni
lai rin irin ajoo lọ sagbegbe to jinna, wọn wa ṣakiyesi pe mi o ni awọn ẹṣọ to
n tẹle mi, bi wọn ṣe bere idi ẹ lọwọ mi, mo wa a sọ fun wọn pe mo mọ daju pe
aarin awọn eeyan mi ni mo wa, ati pe ọkan mi balẹ pe ko si nnkan to maa ṣe mi. Nigba
ta a debẹ, ti wọn ri bawọn eeyan ṣe ya bo mi, o ya wọn lẹnu gidigidi. Emi fẹẹ
da yatọ lati rii pe mo wa larọwọto awọn ti mo n ṣoju, ki temi si yatọ si tawọn
to ti ṣe tẹlẹ.
Nipa awọn to ti wa nibẹ tẹlẹ
Lọdun mẹjọ sẹyin, Ọnarebu
Olumide Ọṣọba lo wa nibẹ, tawọn eeyan ṣi n sọ pe ko ṣe nnkankan fawọn nigba
naa. Ọnarebu Mikky Kassim lo wa nibẹ bayii, mi o si ri nnkan to ti ṣe ni pato
ta a le tọka sii, yatọ si pe o n ra ọkada ati mọto fawọn eeyan, iyẹn kii ṣe pe
o n ro awọn araalu lagbara lọdọ temi. Irolagbara jẹ nnkan tawọn eeyan yoo maa
ri lo titi lai. Ẹni to n fawọn eeyan ni ọkada fẹ ki gbogbo eeyan di ọlọkada
patapata ni, pupọ awọn to n fun ni ọkada yi lo jẹ pe akẹkọ gboye ni wọn jẹ. A ni
awọn ibi ti aaye ti ṣi silẹ lati ṣiṣẹ bii ọlọpaa, ẹṣọ aṣọbode, ẹṣọ oju popona,
ologun abbl, mi o mọ iye awọn to ti mu wọle sibẹ. Ti mo ba debẹ ti mo ri ibi to
ba iṣẹ de, maa tẹsiwaju awọn eyi to dara nibẹ, maa si gbe awọn eyi ti ko dara
ninu iṣẹ to ṣeku pamọ sẹgbẹ kan, maa si tun ṣe nnkan temi naa ni lọkan lati ṣe.
Mo fẹẹ sọ fawọn ara ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode/Ọdẹda ati Abẹokuta North pe ki
wọn lọọ fọkan balẹ lasiko yi, nitori pe ayipada rere n bọ fun wọn. Bawọn tọọgi
ba wa pe awọn fẹẹ fa wahala nibi ti mo ti n polongo, ọrọ abiyamọ ni mo maa n ba
wọn sọ, ti Ọlọrun si n gba ọkan wọn fun mi. Latigba ti mo si ti n kaakiri, ko
tii sẹni to wa a ba mi fa wahala kankan.
Nipa fifi owo ra ibo (vote-buying)
Ko tii pẹ ti wọn gbe eto ki wọn
maa fi owo ra ibo de, awọn ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn si gbe e wa, bo ya a fẹ tabi a
kọ, a gbọdọ sọ eyi to n jẹ otitọ nibẹ, ko si nnkan to n jẹ pe wọn fi owo ra ibo
tẹlẹ, ṣugbọn wọn ti gbe e de bayii. Gbogbo ibi ti mo ti n lọ polongo ni mo n sọ
fun wọn pe bi wọn ba gba lati jẹ ki wọn ra ibo wọn, ọjọ iwaju wọn ti wọn ta
danu yẹn, nitori pe bi wọn ba ta ibo wọn, wọn ko ni anfaani lati sọrọ mọ. Mo n
sọ fun wọn pe ki wọn dibo fun ẹni ti ọkan wọn ba tẹle, iyẹn adije ti wọn ba mọ
pe ipo naa tọ si. Lasiko ta a wa yi, awọn eeyan gan an ko fẹẹ dibo fun ẹgbẹ
oṣelu mọ, nigba ti wọn dibo yan Ọnarebu Mikky, ko sẹni to mọn ọn, wọn kan dibo
fun APC ni. Adije lawọn eeyan fẹẹdibo fun bayii kii ṣe ẹgbẹ oṣelu mọ.
Amọnran mi fawọn eeyan mi
Mo fẹ ki wọn jade lọpọ yantutu
lati dibo fun ẹgbẹ oṣelu PDP, nitori pe ẹgbẹ kan ṣoṣo to le fun wọn ni ayipada
tootọ niyẹn, ko si ẹgbẹ oṣelu to tun le mu ayipada tawọn araalu n fẹ wa, bi ko
ṣe ẹgbẹ oṣelu PDP.
No comments:
Post a Comment